Latari erongba ileeṣẹ Flour Mills of Nigeria Plc lati maa pese ohun-jije fun awon eeyan orile-ede yii, eyi gan-an lo mu un kede ikojade Pasta tuntun ti iwọn re je irinwo giraamu (Golden Penny 400g Pasta pack)
Gege bi ileeṣẹ to n le iwaju laarin awọn ti wọn maa n ṣe ohun-jijẹ, ni bayii, ileeṣẹ to ni ‘Golden Penny’ ti gbe ohun jijẹ mi-in de lakọtun, Pasta ti iwọn ẹ jẹ irinwo ti wa lọja bayii fun anfaani awọn onibaara wọn lati yan aayo ohun ti wọn ba fẹ, bo ti ṣe wa lẹjẹwọn-lẹjẹwọn.
Ounjẹ tuntun ti wọn ṣe ikojade ẹ yii ko sai ṣafihan bi ileeṣẹ Flour Mills orile-ede Naijiria ṣe dangajia to nipa pipeṣe oriṣiriṣi odinwọn Pasta to n ti ileeṣẹ wọn jade, gẹgẹ bi awọn eeyan ti ṣe beere fun un, ti yoo si ba oriṣiriṣi ikojọpọ mu pẹlu.
Pẹlu Pasta tuntun ti odinwọn ẹ jẹ irinwo yii (400g pack), ileeṣẹ FMN ti fidi ẹ mulẹ pe oun yoo tubọ tẹnpẹlẹ mọ ṣiṣe ohun jijẹ ti yoo maa fun awọn eeyan ni okun ati agbara, bakan naa ni eto wa daadaa fun awọn lọkọ-laya tuntun lati maa ri ounjẹ to n ti ileeṣẹ ọhun jade ra daadaa, bo ti ṣe wa loriṣiriṣi, ti yoo si fun wọn lanfaani lati lo o lọna to ba wu wọn ati bi wọn ba ṣe fẹ ẹ si.
Gẹgẹ bi ohun jijẹ ti wọn ṣe latara ohun elo to pọju owo, iyẹn Durum, ileeṣẹ Golden Penny ko sai mu awọn ohun aṣaraloore to le fun ni okun ati agbara, paapaa faitami A ati faiba ni pataki daadaa. Lara awọn ojulowo ounjẹ aladun to n ti ileeṣẹ ọhun jade, to jẹ ko-ṣe-ma-ni fun awọn araalu niwọnyi; Spaghetti, Spaghettini, Macaroni ẹlẹlọọ ati eyi to ri kodoro.
Lasiko ti ọga agba fun ileeṣẹ FMN, Devlin Hainsworth n sọrọ nipa ipo aṣaaju ti ileeṣẹ ọhun wa ni Naijiria, ta a ba n sọ nipa awọn ileeṣẹ to n ṣe ohun jijẹ ati mimu, ọga agba to wa lori eto ipese ounjẹ yii sọ pe, “O ti le ni ọgọta ọdun ti ileeṣẹ wa ti n ṣe oriṣiriṣi ohun-jijẹ fun araalu.
“Orukọ ti gbogbo aye mọ wa si, iyẹn Golden Penny jẹ akọmọna oriṣiriṣi ounjẹ aṣaraloore, to n fun ni lokun ati agbara to n ti ileeṣẹ wa jade, Pasta tuntun oniwon irinwo yii jade latari ibeere awọn araalu ni, bee la ni igbagbọ pe pe tuntun to ṣẹṣẹ jade yii yoo fun awọn eeyan, paapaa awọn mọlẹbi ti wọn jẹ alabọde lanfaani lati ni in, bo ti ṣe wa ninu eto isuna wọn lori ohun jijẹ.”
Ninu ọrọ ọga agba feto kara-kata ileeṣẹ naa, Bisi Idowu lori ounje tuntun ti wọn ko jade yii lo ti sọ pe, “Gẹgẹ bi ileeṣẹ nla, ohun ti FMN duro fun ni lati maa pese ohun jijẹ to dara, eyi to le fun ẹbi, ajọ ati ilu lokun ati agbara, paapaa awọn mọlẹbi tuntun lorile-ede Naijiria.
“Ojulowo ounje aladun to le ṣe ara loore lawọn onibara wa maa ba pade ninu Pasta tuntun oni-irinwo giraamu yii. Irufẹ awọn eroja aṣaraloore ti wọn ti mọ mọ awọn ohun-jije to n jade lati ileeṣẹ wa lati ọpọlọpọ ọdun sẹyin naa ni wọn yoo tun ba pade ninu eleyii.
Pẹlu ohun-jijẹ tuntun yii, erongba ileeṣẹ FMN ni lati ri i pe irẹpọ ti ko lẹgbẹ wa daadaa laarin awọn mọlẹbi tuntun nipa pipese ounjẹ aladun, eyi ti aimoye miliọnu le maa jẹ ninu ile wọn lorilẹ-ede Naijiria.
Lati ọdun 1960 ti ileeṣẹ ọhun ti wa pẹlu awọn ounjẹ wonyi, pasta, semolina, suga, ounje okele, ororo ati awọn nnkan mimu, bẹẹ ni ileeṣẹ ọhun n dagba si i ninu ipese ohun jije, ti ọwọja rẹ si wa kaakiri orilẹ-ede yii.
No comments:
Post a Comment