Ti won ba n so nipa awon eto Islam to laami-laaka lori afefe, ohun to daju saka ni pe won yoo daruko eto Sebilu Nnajat ti gbajugbaja aafa oniwaasi nni, Alaaji Sheik Ahmad Olanrewaju Anifulaany je alakooso ati adari e.
Lori eto yii ni ogunlogo awon eeyan ti je oke aimoye ebun ati owo, bee lawon mi-in ti di onile ati eni to n lo si Meka lori eto yii. Bo tile je pe eto naa ti di igi aloye ti awon eto yooku n wo niwaju, sibe ki I nnkan kekere ni oju Sheik Anifulanny ri ki eto naa too da ohun to da lonii.
Lasiko ti Sheik Anifulanny ba wa soro lo ti so pe ohun toju ri po gan-an. ' Nigba ti a koko bere, a ma n lo kaakiri ile awon eeyan fun ebun ni, mo ranti daadaa pe mo loo ba enikan to n ta aso pe ko fun wa laso lori eto wa lati pin fun awon eeyan, sugbon ohun to so ni pe ko si aso ti oun yoo fi tore fun wa.
Se ni mo loo ya owo fi raso lowo eni yii, ohun ti mo waa se ni pe nigba ti mo dori eto se ni mo n pariwo oruko eni naa pe o fun wa laso ofee. Ohun ti mo se yii jo obinrin yii loju, lonii, eni naa wa lara awon to n fun wa laso, ti won tun mu wa lo si odo awon mi-in.
Nigba to n dahun ibeere bi won n se se awon owo ati ebun ti won n fun won lori eto, Anifulanny ni mo je enikan to ni itelorun lori ohun ti mo ba ni, bi won se ni ka fun awon eeyan la se n fun won, a o ki yo ohunkohun kuro nibe, mo ni itelorun pelu ohun ti Olorun fun mi.
Bakan naa lo so pe eto Sebilu Nnajat ki I se fun igba aawe nikan, o ni eto naa n te siwaju leyin aawe. Aafaa nla yii tun te siwaju ninu oro e pe opo awon eeyan ni won ti je anfaani lowo ileese naa, bii eko-ofee, eni to saisan, eni to ni ipenija ile tabi ohun ti yoo se jeun.
O waa ro ijoba atawon ti Olorun ba bu kun lati ran eto yii lowo, ko ma je lasiko aawe nikan nitori pe awon to janfaani lori eto naa po pupo
No comments:
Post a Comment