IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Friday, 8 October 2021

Olórin tí yóò ṣàṣeyọrí gbọdọ̀ kó ara rẹ̀ ní ìjánu lọ́dọ̀ àwọn obìnrin-Sanmí Michael


Gbajugbaja olorin ọmọ orileede yii to fi Amẹrika ṣebugbe, Sanmi Michale  ti sọ pe olorin to ba fẹẹ lu aluyọ nidi iṣẹ orin gbọdọ ko ara rẹ nijanu lọdọ awọn obinrin. Sanmi Michael tawọn ololufẹ ẹ tun  mọ si Akilẹ Atugba sọ pe loootọ awọn obinrin ṣe pataki lọdọ awọn olorin nitori pe awọn ni iyọ aye ni wọn, wọn si ṣe pataki si gbogbo iṣẹ ti eeyan ba n ṣe, ṣugbọn o ṣe pataki ki eeyan ko ara rẹ nijanu lọdọ wọn, nitori pe ki i ṣe gbogbo obinrin ni olorin gbọdọ kọ ẹnu ifẹ si.

O ni awọn kan wa to jẹ pe alaaanu lasan ni wọn jẹ si wa, ko si gbọdọ si ohun ti yoo pawapọ ju pe wọn jẹ ololufẹ  ati olooore wa lọ. Olorin to ba ni i lọkan pe oun yoo maa ni ibalopọ pẹlu awọn obinrin ti wọn nifẹ rẹ, iru olorin bẹẹ ko le e laṣeyọri nidi isẹ orin, o dara ka ko ara wa nijanu lọdọ awọn ololufẹ wa.

Bakan naa lọkunrin yii sọ pe eto ti n lọ lọwọ lori rẹkọọdu oun to n bọ lọna, eyi to sọ pe ọpọlọpọ alujo ati orin gidi lo kun inu ẹ bamubamu.     


No comments:

Post a Comment

Adbox