Kani gbajumọ oṣere tiata Yoruba nni, Laide Bakare mọ pe oun yoo kabuku oloronbo lọwọ awọn eeyan, o daju pe obinrin naa ko ni i ṣe ohun to ṣe naa, ṣugbọn ko mọ ohun to jẹ ko kabuku nla ọhun ree.
Ohun to ṣẹlẹ ni pe orin kan ni irawọ oṣere fuji nni, Adewale Ayuba gbe jade to pe ni ‘koloba-koloba’, orin ọhun lawọn ololufẹ Ayuba ṣe fidio rẹ ti wọn si fi sọwọ si ọkunrin naa, toun naa si gbe e sori ikanna facebook ẹ. Lara awọn fidio ti Ayuba gbe sori ẹrọ ayelujara yii ni fiido ibi ti Laide Bakare ti n jo si orin ‘koloba-koloba’ yii wa, ṣugbọn ohun to jẹ ki tiẹ yatọ si ti awọn eeyan yooku ni pe ṣe ni Laide patẹ ọyan ẹ mejeeji sita ninu fidio naa, bẹẹ ni ọmọbinrin naa tun yọ awọn sita bo ṣe n jo sorin naa.
Ohun ti awọn eeyan ri niyẹn ti wọn ṣe ju bọmbu ọrọ si Laide Bakare, wọn ni obinrin naa ṣe ohun to jọ awọn loju, wọn ni ki i ṣe iru ẹ ti wọn fi joye Iya Adinni lo yẹ ko ko ọmun ẹ mejeeji sita bẹẹyẹn. Bẹẹ lawọn mi-in sọ pe ohun ti obinrin yii ṣe ko yatọ si ẹni to wa a polowo ọja fun awọn ọkunrin lori ẹrọ ayelujara.
Ohun ti awọn mi-in tun sọ ni pe arikọṣe rere lo yẹ ki Laide jẹ fun awọn ọmọde, ṣugbọn ohun to ṣe yii ko ṣapejuwe ẹ bii ẹni ti eeyan gbọdọ tẹle iwa ẹ lawujọ.
Nibi ti ọrọ yii ka awọn eeyan kan lara de, ṣe ni wọn sọ fun Ayuba pe ko ma jẹ ki Laide Bakare ba a lorukọ jẹ. nitori pe ọlọpọlọ pipe to mọ nnkan to n ṣe ni Ayuba, ko ma jẹ ki Laide ta epo si aṣọ aala rẹ.
Lọrọ kan, awọn eeyan binu si Laide Bakare o, wọn lobinrin naa ba awọn loju jẹ pẹlu bo ṣe patẹ ọyan ẹ sita gbangba.
No comments:
Post a Comment