IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Saturday, 9 October 2021

Bi wọn ko ba sọra ọtọọtọ ni ibo APC ipinlẹ Eko yoo waye- Fouad Oki

Ọkan lara oludije fun ipo alaga fẹgbẹ oṣelu APC, nipinlẹ Eko, ni  Fouad Oki, wọn ti figba kan jẹ igbakeji alaga fẹgbẹ naa, ko to wa di pe wọn jade lati dupo bayii. Ọkunrin naa ba oniroyin wa sọrọ lori erongba ẹ lati dupo ati ibi tọrọ ẹgbẹ naa de bayii.

Kin ni igbaradi to wa fun ibo ẹgbẹ APC tipinlẹ to n bọ lọna ati pe ibo ni ẹ ba ẹgbẹ naa de?

Gẹgẹ bi igbaradi to yẹ ko wa nilẹ lati ara ilana ti ẹgbẹ wa ti gbe silẹ lori, bawo la ṣe maa ṣeto ibo ni isọriisọri, ẹ o ranti pe  nigba ti akọkọ bẹrẹ, ibo awọn to maa ṣe alakoso ẹgbẹ lati ori wọọdi ati tijọba ibilẹ, ipele kẹta ni tipinlẹ ti ẹgbẹ ti fi le lẹ bi eto ọhun yoo ṣe lọ.

O wa ku ki wọn gbe ibo yẹn yoo ṣe ri ati ilana ẹ, ninu ọsẹ yii lo ma a jade ki a to dibo., wọn a gbe ilana naa silẹ. lati mọ iru awọn to yẹ ko dibo ati ọna ti wọn fẹẹ gba di, oun ni a n duro de.

Lori bi ẹgbẹ ṣe de bayii, pẹlu awọn ibo meji taa ti di sẹyin,o digba ta a ba pari ka to rii pe o lami laaka., o ti kun oju osuwọn, a o ti le fẹnu sọ,,  a si tun gbọdọ ma ṣe alaimẹnuba awọn kudiẹkudiẹ to wa nibẹ.

Ninu awọn  taa ti ṣe, nitori awọn ilana ti wọn gbe wa lati ọdọ apapọ ẹgbẹ pẹlu bi awọn igbimọ fidihẹ, niopinlẹ Eko, wọn ṣe aiṣedeede , iwe to yẹ ki a gba, wọn ṣs baṣubaṣu, to fi jẹ pe awọn kan ko ni anfaani lẹyin ti wọn sanwo, ti wọn si mu iwe ẹri pe wọn sanwo wa, ki wọn ba le fun wọn niwe to yẹ ki wọn fi dibo.

Awọn to n ṣe bi alagbara, ti wọn fi agbara han,wọn ṣe idiwọ ẹ, paapaa julọ awọn ikọ temi ati wọn jọ n fikunlukun taa jọ n ṣe ninu ẹgbẹ yii, to jẹ pe ani lati wọ ọkọ lọ si Abuja lati lọ gba iwe naa ni.

Bi wọn ṣe ṣi ni wọọdu naa ni wọn tun ṣe ni tijọba ibilẹ, ohun ti wọn wa sọ ni pe ṣebi gbogbo wa ti fẹnu ko, ki a yọ si ara wọn, ibeeere temi wa n beere nigba ti igbimọ ti wọn gbe kale lori ifehonu han ni pe ti wọn ba sọ pe awọn ti jọ jokoo pẹlu wa ni itunbi-inu-bi, ki wọn sọ ibi ti ijokoo naa ti waye.

Ki wọn si sọ awọn to wa nibi ipade ọhun, ki Ọlọrun fọrunkẹ Baba wa, Moshood Abiọla, wọn a sọ pe  o ko le fa ori mi lẹyin mi,  a bi o le fa, beeyan ko ba lọ sile awọn to n gẹrun, mi o ro pe wọn le fa irun lẹyin ẹ, bi ẹ ba sọ pe gbogbo wa jọ jokoo lati jọ sọrọ, mo ro pe gbogbo ẹni to ba yẹ ko wa nibẹ lo yẹ ko wa, ki i ṣe pe ki ẹyin kan lọ jokoo sibi kan ki ẹ waa ni ẹ ti sọrọ pe bayii lo ṣe maa ṣẹlẹ o.

O jẹ nnkan to ba eeyan ninu jẹ, nitori bi a ṣe gbọn ekuru tan lawo, lawọn kan tun gbọwọ ẹ lawo, to si kọ mi lominu ju ni pe ẹni to ba mọ ẹgbẹ wa daadaa yoo mọ pe ẹgbẹ mẹkunnu ni, amọ awọn kan jokoo si ipo ta lo maa mu mi, ti wọn ko fẹẹ ki ọmọ mẹkunnu ni lari.

Idi temi ati ọmọ ẹgbẹ to gbọ rẹpẹtẹ fi sọ pe ko yẹ ki o maa ribẹ. Ko si gbọdọ ri bẹẹ mọ, nitori to ba jẹ ẹgbẹ mẹkunnu ni, a ni lati  faye silẹ fun ọmọ ti ko ni baba nigbẹjọ ko le di eeyan.

 

Ibo tẹ ẹ di kọja ni nnkan bi ọdun mẹta sẹyin, onikaluku di tiẹ lọtọọtọ ni, ṣe ki i ṣe pe iru ẹ naa lo tun bọ yii?.

 A gbiyanju lọdọ wa ko ma ri bẹẹ, amọ to ba jẹ pe nnkan to ba niyẹn, bi a ṣe maa ṣe ni, latari pe a o nigba ki awọn ti wọn ko fẹẹ ki ẹgbẹ yii ni ilọsiwaju tẹ siwaju lori awọn iwa, to jẹ ijamba eyi ti ko mu ki inu awọn araalu dun si wa.

 A ni lọkan ko jẹ pe wọn a fi aye silẹ ki gbogbo wa jọ jokoo, ki awọn ọmọ ẹgbẹ mu ẹni ti wọn ba yan an layoo, ki i ṣe pe ki wọn maa dunkoko mọ awọn to yẹ ki wọn wa dibo, nitori o ti n ṣẹlẹ, ti wọn gbiyanju lati ba awọn to yẹ ko wa dibo sọrọ, ti wọn sọ pe ki wọn ma gbọrọc si wa lẹnu.

Emi si ti n sọ fun wọn pe bi wọn n ba ṣe bẹẹ lọ, bi a ṣe ṣe e ni idunta, ni a tun maa ṣe e, to jẹ pe ile ẹjọ la lọ, a n ṣe ẹjọ yẹn lọwọ lawọn aṣaaju wa ni apapọ ni pe ki gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ ti wọn tilọ sile ẹjọ pada wa, awọn yoo ṣe atunṣe.

Idi atunṣe yẹn la n ṣe, amọ ti awọn ti mo fẹẹ pe ni atunida ti wọn ro pe awọn Ọlọrun, ti wọn maa sọ pe ko si nnkan taa le ṣe, ti ko ba ti tẹ wa lọrun, ki a fi ẹgbẹ yii silẹ, mo sim maa n sọ fun wọn pe a ko le fi ẹgbẹ yii silẹ, a jọ ni ni. A jọ pilẹ ẹ ni.

Njẹ ipadabọ Bọla Ahmed Tinubu le mu atunṣe ba wahala to n waye ninu ẹgbẹ naa?

Mo kọkọ ki Baba wa pe wọn kaabọ sile, nitori pe iran Odidẹrẹ ki i lọ soko ko ma pada, Ọlọrun ọba a tubọ fun wọn lokun ati agbara.Ko si nnakn ta a le ṣe fun ara wa ju pe ka fi ifẹ han ka si maa gbadura fun ara wa.

Amọran temi fun wọn ni pe bi wọn ṣe de yẹnm, ki wọn si fara soko, bi ọjọ meloo diẹ si, ki ara sile, ko to di pe wọn maa bẹrẹ gbogbo laasigbo, lẹyin naa eto bi a ṣe fẹẹ yan awọn alakoso, eyi to wa niwaju wa,ki wọn gbiyanju lati rii pe ẹni to yẹ loye, ni ki wọn fi sibẹ.

Ki wọn wo ẹni to ba fẹẹ ṣe akoso ẹgbẹ ki wọn da labaa, ki gbogbo ọmọ ẹgbẹ to ba fẹẹ du oye ki wọn jade sita, ki awọn ọmọ ẹgbẹ ni anfaani lati mọ wọn, ki wọn le sọ ẹni ti wọn fẹẹ loye,lati sakoso, ki wọn maa fojo ṣaaju ṣe, ifẹ ati irẹpọ ni ki wọn gbe dani, nitori ko si ifẹ ninu ẹgbẹ wa nipinlẹ yii.

Ko si si irẹpọ to danmọran, to sile ṣakoba fun wa nibi lori ọrọ aarẹ, nitori ile la ti n kọ ẹṣọ rode. A sunmọ awọn eeyan wa ju ara wa lọ, wọn beere pe ki lo de ti ko si ifẹ ati irẹpọ,bi a ba le mu ẹni tawọn ọmọ ẹgbẹ sọ pe a le fọkan tọ, ti wọn foju jọ.

Kin ni awọn eto yin fawọn ọmọ ẹgbẹ yin gẹgẹ bi oludije fun ipo aarẹ?

Eyi to lagbara ju ni  bi a ṣe maa mu irẹpọ wa sinu ẹgbẹ,bi a ọṣe ma jẹ kawọn ọmọ ẹgbẹ mọ pe a o nii ṣe ojuṣaaju, gbogbo ẹni oye ba tọ si, ti anfaani ba tọ si la maa fun.

Ko ni si nnkan to n jẹ oju lagbaja ni mo fẹ, ikẹta, ni pe awọn ẹgbẹ wa kan n ṣe lasan ni, ọpọ wa lo ni anfaani lati ṣe okoowo tabi ọrọ aje. awọn ọmọ wọn to kawee gan an ko riṣẹ, iṣẹ to wa nita, wọn ko nimọ ẹ.

Ọpọ awọn to kawee, wọn ko jẹ ki wọn fiṣẹ ọwọ kun, ti mo ba ni anfaani ti wọn ba yan mi loye laarin oṣu mẹta, a o ṣe eto lati wa iṣẹ fawọn to n ba n wa, ki i ṣe iṣẹ ijọba o, ijọba ko anfaani lati gba awọn eeyan ṣiṣẹ lakooko yii, nitori nnkan ti eti iṣuna n sọ.

No comments:

Post a Comment

Adbox