Ọkan ninu awọn ọdọmọde olorin Islam to ṣẹṣẹ goke agba bọ ni Hajia Jemeelat Muibudeen tawọn ololufẹ ẹ mọ si Temidire, arẹwa obinrin naa n palẹmọ ayẹyẹ iko rẹkọọdu ẹ tuntun to pe ni ‘Igbinyanju’ mọ, bẹẹ lọmọ bibi Awori naa tun fẹẹ fun awọn eeyan kan lami-ẹyẹ.
Ọjọ Sannde, ọjọ kẹta oṣu, kẹwaa ọdun yii layẹyẹ naa yoo waye laafin Ọba Ọlọtọ. Lara awọn eeyan ti wọn yoo gba ami-ẹyẹ lọjọ naa ni: Alfa Mutiu Lateef Akintunde, Alfa Abdulfatai Asaotty, Sheik Abdulrasheed Ọladele, Al Imam Ajikanle Ibraheem, Ọgbẹni Adegoke Alawiye, Hajia Ramọtulahi Ọmọwunmi, Hajia Shadia Issa ati Hajia Shereefat Sulaiman.
Iya ọjọ naa ni Alaaja Oluwashikẹmi Ọlakanmi. Nigba ti awọn alaga obinrin ọjọ naa ni: Arabinrin Hafusat Muti, Arabinrin Alimọt Ọlanrewaju, Alaaja Idayat Muheebudeen, Arabinrin Fatimọt Muibueen ati Arabinrin Rukayat Jamiu.
Awọn olorin Islam ti wọn yoo kọrin nibẹ lọjọ naa ni: Alaaja Jẹmilat Ọpẹyẹmi Alagbe, Seyidat Abikẹ Sabella, Mohammad Jamiu Ọmọnla, Alaaji Abdulrasheed Tayelolu ati Hajia Mujeedah Titilọpẹ Tijani.
Olugbalejo pataki ọjọ naa ni Alaaji Funshọ Humeen Akanji Amọo, aafaa ti yoo ṣe waasi nibi ayẹyẹ naa ni Fadeelat Li-mam Abiọla Akewukawo. Ọba alaye ọjọ naa ni Alayeluwa Ọba Ọlnrenwaju Joshiah, nigba ti iya ọjọ naa yoo jẹ Oloye Awawu Issa Awesu.
Ninu ọrọ ẹ, Jemeelat ni awo oun to n bọ lọna yii ni akọja ewe oun, bẹẹ lo sọ pe ọpọ orin ọlọgbọn tawọn musulumi ododo gbọdọ ni nile wọn lo kun inu ẹ bamubamu. Ọdọmọde akọrin islam yii fi kun ọrọ ẹ pe lati kekere loun ti n kọrin ati pe baba oun ko kọkọ fọwọ si i ki oun kọrin afigba ti orukọ oun bẹrẹ si ni i jade laarin awọn ẹlẹgbẹ oun lo too gba fun oun. Jemeelat ni mama oun nikan lo faramọ ọn nigba ti oun kọkọ bẹrẹ. O wa a rọ gbogbo awọn ololufẹ ẹ lati fi ọjọ naa yẹ oun si.
No comments:
Post a Comment