IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Thursday, 26 August 2021

Gbajugbaja Olorin Islam,Fátímòt Ẹyinjú Ànọ́bì Fee sayeye nla lEkoo

   

Gọngọ yoo sọ lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrin osu kẹsan-an, ọdun yii,  ọjọ naa ni ọkan ninu awọn gbajumọ olorin Islam lorileede yii, Hadja Abdulsalam Fatimọt Ẹyinju Anọbi yoo ṣayẹyẹ onibẹta. Ayẹyẹ ọhun ni fifun awọn eeyan lami-ẹyẹ, ifilọlẹ rẹkọọdu ẹ tuntun ati wife lawani fun awọn lami-laaka kan.

Gbongan ‘Combo Hall’ to wa ninu ọgba ileeṣe tẹlifiṣan LTV 8 layẹyẹ naa yoo ti waye. Awọn olorin ti yoo dalu bolẹ lọjọ naa ni King Saheed Akoree Osupa ati Alaaji Abdulazee  Abiọdun Saoti Arẹwa atawọn olorin islam mi-in. Rẹkọọdu ti obinrin naa fẹẹ ko jade bii ọmọ tuntun ni wọn pe akọle rẹ ni ‘Ọmọ Tooni’. Oniwaasi ọjọ naa ni Sheik Abubakar Issah Baba Ọtẹ.

lara awọn alejo pataki ti wọn n reti nibi ayẹyẹ na ni:Alaaji Afeez Olalekan Yusuph

 Alaaji  Ibraheem Olaniyan, Alaaji Ahmod Adeshina Abdulsalam,  Alhaja Mariam Bakare  atawọn eeyan jankanjankan mi-in

No comments:

Post a Comment

Adbox