IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Thursday, 12 August 2021

Ninu eje mi lorin wa, Sanmi Michael, Gbajugba Olorin lo so bee



Okan gboogi ninu awon omo orileede yii ti won n fi ebun ti Olorun fun won gbe ogo Naijiria ga loke-okun ni King Dairo Oluwasanmi  Adeniyi tawon ololufe e mo si Sanmi Michael Akile Tungba. Okunrin naa ki i se eeyan kekere lorileede Ameirika to n gbe.


Laipe yii lokunrin naa ba wa soro, ninu alaye e lo ti so pe lati kekere loun ti korin, okan ninu awon to korin pelu awon agba olorin bii Victor Olaiya ati Adeolu Akinsaya ni baba to bi I lomo, bee ni mama e tun je adari awon olorin ninu ijo.

Yato si pe Sanmi Michael je ogbontarigi olorin, gbajumo olorin naa tun mo awon irinse orin lo daadaa.

 
Ileewe  'Sacred Heart Private School Onireke ibadan, lokunrin naa lo, bee lo tun kawee ni  
Molusi College, ijebu igbo,Ogun state.

Ileewe  Ladoke Akintola University of technology to wa ni  Ogbomosho lo ti kawee ninu imo 'Agricultural Economics and Extension.


Awon olorin to pe ni akegbe e ni Femo Lancaster, Lanre Atorise ati Yinka Adonia.


Rekoodu meji losere nla yii ti gbe jade, awon rekoodu ohun ni 'Thanksgiving ati Praise Time' nigba to pe eleeketa ni 'My Time'. ri yoo jade ninu osu kejila odun yii.

 Bee lo  fi kun oro e pe Sir Shina Peters ati Yinka Ayefele lawokose oun ninu ise orin.


Sanmi Michael ninu oro e so pe orin aladun,orin ope ati alujo ti ko legbe lawon eeyan yoo ba pade ninu rekoodu 'My Time' to n bo lona yii. O te siwaju ninu oro e pe oun tun fi rekoodu naa dupe lowo awon ololufe oun fun aduroti won latigba toun ti here orin.

No comments:

Post a Comment

Adbox