IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Sunday, 30 May 2021

Won fee fi ija awon olopaa atawon omo egbe okunkun ni Agura Gberibe ba mi loruko je ni- Otunba Kamorudeen Sirkay Oluwo


Lọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja lọhun-un, ni wahala kan bẹ silẹ ni abule ti wọn pe ni Agura Gberigbe, Ikorodu, nipinlẹ Eko, laaarin awọn ọlọpaa atawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun,nibi tawọn mẹta ninu awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa ti jẹ Ọlọrun nipe.

Gẹgẹ bi iwadii wa, wọn niluu Abuja lawọn ọlọpaa kogberegbe SWAT ti wa si abule ọhun lati wa ṣe awọn iwadii lori lẹta  ẹhonu ti ẹnikan kọ si wọn lọhun-un lori ọrọ ilẹ.

Ṣugbọn wọn ni bawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ṣe gbọ pe awọn ọlọpaa ti wa ni abule ọhun, ṣe ni wọn ko besu bẹgba tawọn naa fi lọ sibẹ lati lọ koju wọn. Fun bi ọpọ wakati lawọn ara abule yii fi wa ninu ipaya lakooko tija yii n lọ lọwọ.

Wọn lawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yii ko mu ọrọ naa ni kekere, nigba ti yoo si fi rọ meji ninu wọn ti ku ku ibọn lati ọdọ awọn ọlọpaa naa nigba ti yoo si fi di ọjọ kẹta lara wọn to tun faragbọta naa tun jade laye, ni wọn fi jẹ mẹta  ninu wọn to ba iṣẹlẹ yii lọ.

Iwadii fi ye wa pe wọn ni ọkunrin kan tinagijẹ n jẹ Koboko, toun jẹ ajagungbalẹ lo ran awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yii lati lọ koju awọn ọlọpaa. 

Latigba ti wahala naa ti waye lawon eeyan ti n gbe e kiri  nigboro pe Ọtunba Kamọrudeen Lamina, tawọn eeyan ẹ mọ si Sir K Oluwo,  to jẹ gbajugbaja oniṣowo ilẹ ati ile niluu Ikorodu mọ nipa iṣẹlẹ yii, wọn tiẹ sọ debi pe oun gan-an lo ran awọn ọlọpaa wọnu abule naa lọ.

 Ọkunrin  ti wọn fẹsun kan ọhun lakooko to n ba awọn oniroyin sọrọ sọ pe oun ko fẹẹ sọrọ tẹlẹ nipa iṣẹlẹ naa amọ bawọn eeyan ṣe n pe oun lo jẹ koun fesi sita ati pe bi wọn ṣe n gbe iroyin ti ko jẹ ootọ naa sọju ẹrọ ayelujara loun ṣe fẹẹ tan imọlẹ sọrọ yii.

O ni lakọkọ oun ko mọ nnkankan lori wahala to waye ọhun, nitori oun ko mọ bawọn ọlọpaa ṣe wa ati nnkan ti wọn waa ṣe. Bi wọn ṣe waa n pariwo orukọ oun jẹ eyi to ba oun lọkanjẹ ju.

Ninu ọrọ ti Promise Effiong, to jẹ agbẹjọro ọkunrin naa sọ lorukọ ẹ lo ti sọ pe irọ funfun balau ni pe onibaara oun wa nibi tija naa ti waye pe oun lo ṣaaju awọn ọlọpaa wa, o ni ko si oootọ ninu ọrọ naa.

Agbẹjọro naa tun ṣalaye pe ko to akoko naa lara onibaara oun ko ti ya to si wa ni ọsibitu kan ti wọn pe ni Divine Mercy lati ọjọ kẹẹẹdogun  si ọjọ kejilelogun, oṣu yii, nibi ti wọn ti n ṣe itọju ẹ.

O wa beeere pe bawo lẹni to wa nile-iwosan nibi to ti n gba itọju yoo fi wa nibi ti wọn ti n ja. Bẹẹ lo tun sọ pe onibaara ẹ yii ko mọ nnkankan nipa ọrọ wahala ilẹ to n ṣẹlẹ labule yii ati pe ninu ọdun yii, ẹẹmeji pere loun de abule naa.

Alaaji Kamọrudeen wa sọ pe oun jẹ ẹnikan to bọwọ fun ofin, to si tun gba alaafia laaye ko sigba kan ti wọn le ri oun ninu wahala. Nitori idi eyi ki awọn to n sọ isọkusọ maa ba orukọ oun jẹ lori ọrọ toun ko mọwọ mẹsẹ.

Ninu ọrọ Ọmọọba Muyiwa Adejọbi, agbẹnusọ fawọn ọlọpaa nipinlẹ Eko, nipa wahala to waye naa, o sọ pe oun ko gbọ nipa iṣẹlẹ yii, wọn ko si ti sọ nipa ẹ foun rara.

No comments:

Post a Comment

Adbox