IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Monday, 31 May 2021

Ọwọ́ tẹ báálé-ilé tó jí adìyẹ ọ̀gá ẹ̀ gbé, wọ́n ló pẹ́ tó ti n ṣé e


Ọmọkunrin kan ti orukọ n jẹ Bamidele to fẹran lati maa ja ọga ẹ lole lọwọ ti tẹ bayii, ti wọn si ti fa ọkunrin naa le awọn ọlọpaa lọwọ.

Gẹgẹ bi Gbelegbọ ṣe gbọ, ileeṣẹ ti wọn ti n sin adiyẹ ati awọn nnkan ọsin mi-in lọkunrin tọwọ tẹ ọhun sisẹ, o ṣi ti pẹ diẹ ti ọmọkunrin naa ti n ja ileeṣẹ naa lole ko too di pe ọwọ tẹ ẹ. Ohun ti a gbọ ni pe ṣe ni Bamidele yoo yọ kẹlẹkẹlẹ lọwọ alẹ lọ si ibi ti wọn n ko awọn adiyẹ yii si, nigba mi-in o le ko adiyẹ mẹrin tabi ju bẹẹ lọ, ti yoo lọọ ta a ni gbanjo fun awọn to n ra a lọwọ ẹ.

Lọjọ ti aṣiiri ọkunrin naa yoo tu, ọkan ninu awọn oṣiṣẹ ẹgbẹ ẹ ni wọn lo ta ọga ileeṣẹ yii lolobo pe Bamidele ma n ji adiyẹ ileeṣẹ naa ko lọọ ta ni gbanjo. Ni wọn ba dẹ pakute silẹ fun un, gẹgẹ bi iṣe rẹ, alẹ ni Bamidele tun yọ lọ si ibi ti wọn ko awọn adiyẹ yii si, ni wọn ba ra a mu. Ọjọ yii laṣiiri ọkunrin naa tu, lojuẹsẹ ni wọn fa a le awọn ọlọpaa lọwọ, ti ọkunrin naa si ti jẹwọ pe loootọ loun ja ileesẹ naa lole.

Ọga ileesẹ naa ninu alaye to ṣe sori ikanni twitter lo ti sọ pe adiyẹ ti Bamidele ti ji gbe ko din ni ọọdunrunlelaadọta laarin asiko ti o fi n ba awọn ṣiṣẹ yii. Ọkunrin yii ni ki i ṣe gbese kekere lọkunrin naa ti ko awọn si bayii, lara ohun to  n fa ifaṣẹyin fun ileeṣẹ awọn niyẹn.

Gbogbo awọn eeyan ti wọn gbọ ohun ti ọkunrin yii ṣe ni wọn rọjo epe le e lori, wọn ni ota aje kan bayii lọkunrin naa n ṣe.

 

O ma ṣe o: Adeọla ku sinu ijamba mọto, afẹsọna ẹ naa wa lẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun

Titi dasiko yii lawọn obi ọmọbinrin kan ti orukọ n jẹ Mariam Adeọla si n banujẹ, ọgbẹ ọkan ni iku ẹ jẹ fun  awọn obi ẹ atawọn to sunmọ ọn pẹlu bi arẹwa obinrin naa ṣe padanu ẹmi ẹ ninu ijamba mọto to ṣẹlẹ si oun ati ololufẹ ẹ.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, inu mọto ololufẹ Adeọla  la gbọ pe awọn mejeeji wa lọjọ buruku esu gbomimu yii, ere asapajude ti ọmọkunrin naa sa lọjọ naa lo jẹ ko lọọ kọlu sọọbu kan lojuọna Ẹdẹ, nipinlẹ Ọṣun, lojuẹsẹ ni wọn gbe Adeọla ati afẹsọna ẹ yii lọ si ilewosan, ṣugbọn bi wọn ṣe gbe wọn debẹ ni ọmọbinrin naa jade laye, ti ololufẹ Adeọla yii wa lẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun.

Akẹkọọ ileewe Yunifasiti Ọbafẹmi Awọlọwọ to wa ni Ile-Ifẹ, nipinlẹ Ọṣun ni wọn pe Adeọla, kilaasi kẹrin ni wọn sọ pe o wa ninu imọ ilẹ okeere to n ṣe nibẹ.       

Ninu ọrọ ibanikẹdun ti awọn ọrẹ Adeọla fi sori ẹrọ ayelujara ni wọn ti sọ pe awọn ti padanu ọrẹ awọn pataki, wọn ni iku to pa ọmọbinrin naa ko ṣe daadaa rara. Wọn ṣapejuwe Adeọla bii arẹwa obinrin to fẹran gbogbo eeyan. Ohun ti awọn eeyan sọ ni pe ọgbẹ ọkan nla niku ẹ jẹ fun awọn to bi i nitori pe wọn ti na ọpọlọpọ owo le e lori ki iṣẹlẹ aburu yii too sẹlẹ si i.


No comments:

Post a Comment

Adbox