Lati fi samin ayajo ojo ti won la sile fun aisan eje ruru lagbaaye, 'World Hypertension Day', ajo kan ti ki I se tijoba toruko e n je, 'FAJIM Medicare Foundation' pese itoju ati ayewo ofe fun awon olugbe Ilasama, ni Mushin, nipinle Eko. Ana, ojo keeedogun, osu yii leto ilera ofe naa waye.
Okere tan, awon eeyan to le ni ogoje (140) ni won janfaani ayewo ofe lori awon aisan bii: ejeruru, ito sugar, hepatitis ati kokoro HIV.
Bakan naa ni won ti se orisiirisii ayewo oyan fawon obinrin ati ayewo Kansa ti won n pe ni prostate cancer fawon okunrin peluu. Opo awon eeyan yii tun janfaani oogun ofe, bee lawon mi-in ti won nipenija awon aisan mi-in naa janfaani ayewo ofe, ti won si dari won sodo awon Akosemose lori imo isegun oyinbo.
Lara awon anfaani ti awon eeyan je lojo naa ni idanilekoo lori ohun to sokufa eje ruru ati bi a se le toju ati dena e. Oludasile ajo FAJIM Medicare Foundation, Ojogbon Fatima Abdulkareem ni won se idanilekoo naa fawon eeyan lojo naa.
No comments:
Post a Comment