IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Sunday, 16 May 2021

Adewale Ẹlesoo Jẹwọ: Loootọ ni mo ṣe ipolongo ibo fun ẹgbẹ APC nipinlẹ Eko, emi o gba owo kankan lọwọ Tinubu o


Ọkan gboogi ninu awọn agba-ọjẹ elere ori itage ni Ọmọọba Adeoye Adewale Ẹlẹsọọ, ilẹ ta si i ti ọkunrin naa ti n ba irin-ajo ẹ bọ nidi ere ori itage. Lọwọ yii oun ni aarẹ ẹgbẹ oṣere ANTP. Laipẹ yii lọkunrin naa ba Gbelegbọ sọrọ, asiko ifọrọwerọ naa lo sọ itan igbesi aye ẹ ati ọpọ nnkan ti awọn eeyan ko mọ nipa ẹ fun wa. Ẹ ma a ba wa ka lọ

Ẹlẹsọọ  lawọn eeyan mọ yin si, ẹ darukọ yin fun wa lẹkunrẹrẹ.

  Adeoye Adewale Alabi Ẹlẹsọọ  lorukọ mi

Ere ori-itage, bawo lẹ ṣe bẹrẹ?

Ha, ọjọ ti pẹ, ibo ni mo ti fẹẹ bẹrẹ gan-an, iṣẹ ti a n ṣe lati ogogji ọdun le diẹ ṣẹyin, ijapa ko le e rin, ahun ko le e sare, kẹrẹkẹrẹ o ti Ile-Ifẹ de Ikirun. Lati aye  fiimu ti wọn n pe ni sẹlilọọdi ni mo ti n ṣe tiata, bẹẹ ni mo kopa daadaa ninu eyi ti wọn pe ni ọpitika naa. Mi o ti ẹ ranti iye ere  ori-itage ta n pe ni siteeji pilee ti mo ti kopa ninu ẹ. Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun pe a ko si ninu awọn ero ẹyin ninu awọn elere ori-itage ilẹ yii.


Ta ni ọga yin nidi iṣẹ tiata?

Awọn ọga mi pọ gan-an, ṣugbọn mo bẹrẹ pẹlu Alagba Fẹmi Olugọga niluu Ilọrin. Mo ti da ẹgbẹ tiata temi silẹ ko too di pe mo pade wọn, lasiko ti mo n sọ yii, ko si tẹlifiṣan meji ni gbogbo Ilọrin to ju ileeṣẹ tẹlifiṣan NTA lọ. 

Mo lọọ ṣe redio mọto mi lọdọ wọn, nitori pe wọn tun mu iṣẹ rẹdionikii mọ iṣe tiata. Bi wọn ṣe ri mi wọn sọ pe awọn ni Baba Kudi, emi naa da wọn lohun pe emi ni Ẹlẹsọọ, a jọ ṣawada lọjọ naa. Ọkọ akọkọ ti a ra ninu ẹgbẹ tiata wa, a jọ da owo ẹ ni. 

Niwọngba to jẹ pe emi ni mo lọọ ba wọn ninu ẹgbẹ wọn, mo le sọ pe awọn ni ọga mi, ọpọ ọgbọn ati ẹkọ ni mo ri kọ lọdọ wọn. Lasiko kan, awọn obi wọn sọ pe ki wọn ma ṣe tiata mọ, wọn ṣalaye fun mi, ṣugbọn mo jẹ ko ye wọn pe emi ko ṣetan lati fi iṣẹ tiata silẹ o.

Loootọ, nnkan ko rọgbọ nigba naa, ọwọ ọlọwọ, ẹsẹ ẹlẹsẹ ti oku n ba wọ saare la n ṣe nigba naa. Bii ka lọọ ṣere ko ma yọ owo, ṣugbọn  ẹmi kan n sọ fun mi pe ki n ma yisẹ pada ninu ohun ti mo n ṣe yii, mo dupẹ lọwọ Ọlọrun pe o mu wa de ibi ti a de lonii. Ni gbogbo asiko yii, mo n ṣisẹ pẹlu ileeṣẹ Atlas.

Ti  a  ba wo o daadaa, lasiko ti ẹ bẹrẹ  ko ti i si owo nidii iṣẹ tiata, awọn nnkan wo loju  ri?

Ha, ko si owo rara, ohun ti ko jẹ ki n tete fẹyawo niyẹn, nitori mi o fẹ ki awọn ọmọ mi rare, mi o fẹ ki wọn ma ni ẹkọ to yanranti, mo fẹ ki wọn kawe de oju amin. Mo wo o pe ti mo ba n gbin ọmọ bii ẹni gbin isu, ko ni i fun mi lanfaani lati tọ awọn ọmọ yii daadaa, nigba ti ko si isẹ mi-in lọwọ mi to ju iṣẹ tiata yii lọ, o le gan-an. 

Lasiko ti emi ati ọga mi yẹn pinya ni mo mọ mama to bi Alaaji Koliighton ni Ilọta, a gbe ere wa lọ si Ilọta, Ajumọni, Ọmọdẹ. Obinrin kan wa to gbe oyun wa lati Eko, bẹẹ lo ni ọmọ kekere kan to n tọ lọwọ nigba naa, obinrin yii ni mo lo lati jẹ ọkan ninu awọn obinrin ti mo lo ninu awọn ere mi, nitori pe ko si obinrin nigba naa ti wọn n gba ko ṣe tiata. 

Asiko yii awọn aafaa Ilọrin ko fi bẹẹ nigbagbọ ninu ere ori-Itage, wọn nigbagbọ pe oloogun ni wa, wọn ko mọ pe ko ri bẹẹ, ko rọrun lati goke ni Ilọrin.Igbagbọ awọn ara Ilọrin ni pe ẹlẹbọ ni gbogbo awa ti a n ṣe ohun to ba jọ mọ ariya, i ba jẹ onifuji tabi onitiata, o ma n nira ki wọn too mọ onitiata tabi olorin to n gbe niluu Ilọrin, wọn n ki rọwọ mu bii awọn akẹgbẹ wọn to ba wa lawọn ilu bii Ibadan, Abẹokuta, Eko tabi Osogbo.

 Mi o waa mọ boya o ti yatọ lasiko yii, ṣugbọn nigba ti awa bẹrẹ ko rọrun ki eeyan maa gbe ni Ilọrin ko rọwọ mu.

Ọmọ ti mo sọ pe obinrin to gbe oyun wa lati Eko yii n tọ lọwọ ni mo gbe kọrun pẹlu ilu akuba, lojiji ni ọmọ yii yagbẹ si mi lọrun, ọmọ ọlọmọ, ko ṣe e la mọlẹ, ko ṣe e lu, omi abata ati koriko ni wọn fi nu gbogbo ara mi lọjọ naa. Nigba ti a de ilọta lọdọ Mama Alaaji Kolighton ni mo too ri omi fi wẹ.

Ọjọ kan la tun lọọ ṣere nibi kan ni, ṣugbọn owo to wa lọwọ wa ko kọja otẹẹli ọjọ kan ni ilu Omuaran,  a si tun ni ere nilu Ọfa  lọjọ keji, a ri gbọngan kan to jẹ pe ko yẹ ọmọ eeyan lati sun sibẹ, ibẹ ni a fẹẹ fọgbọn sun si, ṣugbọn bi a ṣe debẹ ni ọkunrin were kan to n sun ibẹ jade si wa to sọ pe a tun fẹẹ le oun kuro nibi ti oun si. 

Mo sọ fun awọn ọmọọṣe mi pe ṣe ẹyin ko gbọ ohun ti ọkunrin yii sọ ni, o ni a fẹ ẹ le oun jade nibi ti oun sun si, mo ni ki wọn ma jẹ ki a le e jade, inu mọto la sun si loru ọjọ naa. Ki Ọlọrun ṣaanu fun wa, meloo ni mo fẹẹ sọ. Gbogbo idojukọ yii ko sọ pe ki n pada nidi ohun ti mo n ṣe yii, ohun ti mo ba nigbagbọ lori ẹ mi ki i pada nidi ẹ.

Iha wo lawọn obi yin kọ yin kọ si ere ori-itage nigba ti ẹ bẹrẹ?

Ko si obi to faramọ ọn ki ọmọ ẹ ṣe tiata nigba naa, mo ranti ọjọ kan ti a fẹẹ ṣere ni ilu Ikirun to jẹ ilu baba mi, mi o mọ pe baba mi wa lati ile-Ifẹ, yara kan ati palọ ni baba mi n lo nigba naa, bi wọn ṣe de Ikirun ni wọn ba awọn ọmọ ẹgbẹ mi ninu yara ati palọ wọn ti mo ti ja kọkọrọ ẹ, bi wọn se de  ni wọn beere lọwọ awọn obinrin ile pe awọn wo lo wa ninu yara awọn, ohun ti awọn yẹn sọ fun wọn ni pe awọn ọmọ ẹgbẹ mi ni.

 Gbolohun akọkọ to jade lẹnu baba mi ni pe ṣe mo si  maa foju kan Adewale bayii, awọn obinrin ile da wọn lohun pe n o wale lalẹ. Bi mo ṣe n bọ pẹlu apoti ẹgbẹ wa lori ni mo pade baba mi, wọn ni ha, Alabi ki lo de to fi iṣẹ kọnpini silẹ, mo sọ fun wọn pe ohun to wu mi lọkan ni tiata ati pe mo mọ ọn daadaa, wọn ni to ba jẹ pe ohun to wu mi niyẹn, Ọlọrun yoo fi alubarika si i.

Nigba ti mo pada de ile lalẹ, mi o ba wọn nile mọ, ohun ti awọn iyawo ile sọ fun mi ni pe nitori awọn ọmọ ẹgbẹ mi to wa ninu yara wọn ni wọn ṣe pada si ibi ti wọn n gbe, wọn ko fẹẹ di wa lọwọ. O ṣe mi laaanu pe lasiko ti nnnkan n ṣe daadaa ti mo ti wa nipo lati ṣe ẹtọ ọmọ fun baba ẹ ni wọn jade laye.

Asiko wo ni orukọ yin yọ laarin awọn ẹlẹgbẹ yin?

Mi o mọ ọn o, ṣugbọn mo le sọ pe pẹlu iranlọwọ awọn ọga mi mẹrin lo fi mi han faye, awọn ni Ọla Ọmọnitan ti wọn ṣe ere Ọmọ Araye le, mo ṣe Baba Ilọrin nibẹ nigba naa,  ikeji ni Ọga-Bello pẹlu ẹgbẹ awada kẹrikẹri, wọn ṣe ere kan to jẹ ere oloyinbo ati adamọdi oyinbo , mo ṣe Mallamu Garuba Bature ninu ẹ. Ẹkẹta ni ere Ọga mi Ade-Love, awọn ni wọn mu wa si Eko. Ẹkẹrin ni ere ọga mi  Alaaji Ibraheem Aliu Ray Balinga ti gbogbo aye Ray Eyiwunmi. Agbajọwọ okiki ni Ọlọrun fun mi.

Oloṣelu niyin, ki lo gbe yin de idi oṣelu?

Mo ba wọn ṣeṣolu daadaa, nitori eeyan  kan ni eeyan ṣe ma n soselu, paapaa ti wọn ba sọ pe ẹni naa daa, ti awọn eeyan n ti ara iru ẹni bẹẹ dide, ti emi naa tun waa ṣe iwadii ẹni naa ti mo ri i pe eeyan daadaa ni, mo ma tẹlẹ ẹni naa. Oṣelu ti mo n ṣe daadaa ni ti Eko yii, mo ba wọn ṣoṣelu lasiko baba wa Asiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu, mo ba wọn ṣoṣelu nigba baba wa Amofin Babatunde Raji Fashọla, mo ṣe rẹkọọdu fun Fashọla nigba naa,  mo ṣe orin ati ewi fun wọn. Bẹẹ ni mo tẹle Gomina Akinwunmi Ambọde, bẹẹni mo bawọn polongo fun gomina wa to wa nipo bayii, Alagba Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu.

 Ohun ti a gbọ ni pe owo rọburọbu ni wọn gbe fun yin lasiko ibo gomina ipinlẹ Eko. Wọn ni lati asiko Asiwaju to fi de ori Sanwo-Olu lẹ fi n gba owo nla. Ṣe loootọ ni?

 

Walahi mi o gba owo lọwọ baba wa Asiwaju Tinubu, eeyan daadaa ni wọn, ti eeyan ko ni i duro de owo ko too tẹle wọn, mo ṣe e nitori ifẹ ti mo ni si wọn ni. Ifẹ ti mo ni Aṣiwaju naa lo jẹ ki n tẹle egbe wọn di asiko yii, emi ko gba owo. Wahala ti mo ṣe lasiko ibo Ambọde ki i ṣe kekere, lasiko ipolongo ibo Ambọde ni mo pade alaga ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Eko tẹlẹ, Alagba Henry Ajomale ninu ọgbọ ileesẹ tẹlifiṣan LTV. Bi wọn ṣe ri mi ni wọn beere pe kin ni mo n ṣe ninu ọgba naa, mo sọ fun wọn pe mo wa a ṣe faaji ni.

 Wọn ni ibi ipolongo Ambọde lo yẹ ki n wa, wọn beere pe ṣe emi ko mọ pe ẹgbẹ awọn ti bẹrẹ ipolongo ni, mo da wọn lohun pe Ọlọrun yoo fun wọn ṣe, wọn ni ṣe ohun ti mo ma sọ niyẹn, wọn ni mi o ki n ṣe eeyan Aṣiwaju, mo sọ fun wọn pe eeyan Aṣiwaju ni mi, wọn ni to ba ri bẹẹ ki n ba awọn ni ile ẹgbẹ awọn ni Agidingbi. Bi mo ṣe ti ara bọ ọ niyẹn, ko si ibi ti mi o ba wọn de, mi o le gbagbe ohun ti oju mi ri nibi ipolongo APC ni Ibeju-lEkki, ibi ipolongo yii ni mọto mi bajẹ si. Bi Aṣiwaju ba ṣaanu emi naa, ko buru, baba ran ọmọ rẹ lọwọ ni, ki wọn siju aanu wo mi ki emi naa gba ẹtọ mi lori igbiyanju mi ki ẹgbẹ wa le rọwọ mu nipinlẹ Eko.

 

 Ki wọn lọọ wo awọn fidio ipolongo naa, ko si ibi ti wọn gbe ipolongo lọ mi o gori siteeji ṣe ipolongo.

 

Mi o le gbagbe ohun ti oju mi tun ri lasiko ipolongo gomina Sanwo-olu. Eyi ti mi o le gbagbe leyi to waye ni ladojukọ ileewe awọn ọlọpaa to wa  ni Ikẹja, asiko ipolongo yii lawọn onimọto agbegbe naa n ba ara wọn ja, oju mi ri mabo lọjọ naa, inu wahala naa ni foonu olowo iyebiye ti mo ra lati Dubai sọnu si. Emi o si lara awọn to gba owo. Ohun to ṣẹlẹ yii ko sọ pe ki n fi Aṣiwaju silẹ, iroyin rere ti mo n gbọ nipa baba yii ma n dun mọ mi ninu.

 

Ko si iru wọn ninu awọn oloselu wa, Aṣiwaju to n fẹ daadaa fun gbogbo aye ni wọn, ki I ṣe iru aṣaaju rere ti eeyan yoo kuro lẹyin ẹ ni wọn. Mo mọ ọpọ ninu awọn oṣere ẹgbẹ mi ti wọn ri nnkan gidi gba lọwọ  wọn, ṣugbọn ni temi mi o gba kọbọ lọwọ aṣiwaju, afi ti wọn ba fun mi lọla.


Ọmọọba ni yin, ẹ ṣalaye fun wa nipa awọn obi yin

Ọna meji ni mo ti jẹ ọmọọba, ọmọọba ni mi nilu ikirun, bẹẹ ni baba mi tun jẹ baalẹ ni Ile-Ifẹ, ilu ti baba mi ti jẹ baalẹ, wọn ti n jẹ ọba nibẹ bayii, lati aye Ọba Okunọla Sijuade ni wọn ti n jọba nibẹ, ilu Kajọla lorukọ ilu naa, abule mẹfa lo wa labẹ ilu ti baba mi jẹ baale jẹ le lori. Bi mo ṣe jẹ ọmọọba ni Ikirun, bẹẹ ni mo jẹ ọmọọba ni Ile-Ifẹ.

Lapapọ fiimu meloo lẹ ti gbe jade funra yin?

Fiimu ti mo ṣe jade jẹ mẹjọ, mo ṣẹṣẹ pari ikẹsan-an ni, wahala to wa ninu fiimu sise ki i ṣe kekere rara. Eyi ti mo ṣẹṣẹ ṣe yii, ọla ẹjẹ mi, ọmọ ilu mi ti Ọlọrun pe ni alaanu mi ti wọn ko ri mi ri, to si wa ninu erongba wọn pe lọjọ ti awọn ba ri mi awọn yoo ṣe mi looore, awọn ni Ọlọrun lo lati ya fiimu mi ti mo ṣẹṣẹ pari yii. O dun mi pe wọn o ki n fẹ ki eeyan darukọ wọn, mi o ba arukọ wọn fun yin.

Fiimu ti mo ṣe gbẹyin, mo jẹ gbese gidi lori ẹ, ti a lọọ ko awọn alayederu ni Alaba, bi a ṣe lọọ ko awọn ọmọ Igbo yii ni ọkan ninu wọn sọ pe Ẹlẹsọọ mo mọ yin o, ṣebi ẹyin ni ẹ kopa Mallamu  Garuba ninu ere Ọga Bello. Ọmọkunrin yii sọ pe adigunjale loun tẹlẹ, koun too darapọ mọ awọn to n ṣe ayederu fiimu, bẹẹ lo n pariwo pe oun mọ mi, o ni eyi ti ohun ti n ṣe ni a tun fẹẹ le oun kuro nidi ẹ. Ariwo oun mọ mi ti ọkunrin yii n pariwo  lo jẹ ki n sọ pe ki wọn fi i silẹ, ko ma lọọ di nnkan mi-in mọ mi lọwọ. Awọn alayederu yii n koba iṣẹ wa pupọ.

Lara ohun ti awọn eeyan fi mọ yin daadaa ni ọrọ ẹnu yin, awọn kan tiẹ n pe yin ni ẹnu-n-ja-waya. Ibeere mi ni pe nibo iẹ ti ma  ri awọn ọrọ nla ti ẹ ma n sọ ninu fiimu yẹn?

Mimọ rẹ Ọlọrun, imọ kan ko si fun mi a fi eyi ti Ọlọrun ba fi mọ mi, bẹẹ ni mo jogun ẹ lara baba mi. Lasiko kan Gbenga Adewusi polowo fiimu kan, wọn ni Ọmọọba Jide Kosọkọ Ofridọma, Babatunde Omidina Aarẹ Atuwe of Naijiria, Adewale Ẹlẹsọọ Enu-n-ja-waya. Emi ko gbọ ipolowo yii  afigba ti mo dele ti ọmọ  mi, ọmọ ọdun marun-un pariwo ‘ Ẹnu-n-ja-waya, jawayajawaya, mo ni iyalaya ẹ wo lo n ja waya, waya wo ni wọn n ja nile awọn iya rẹ. Iya rẹ  lo jẹ ki n mọ pe Gbenga  Adewusi lo polowo fiimu to pe mi ni Ẹnu-n-ja-waya ninu ẹ, o ni ninu ipolowo naa ni ọmọ mi yii ti gbọ orukọ naa.

Ninu gbogbo orukọ ti mo n jẹ ninu ere ko si eyi ti mo pe ara mi ninu ẹ. Awọn kan naa ni wọn ni wọn pe mi Adewale Ẹlẹsọọ ẹlẹnu kebu, ni Akurẹ awọn kan pe mi Itan foriti, ni Ibadan awọn kan tun pe mi Adewale Ẹlẹsọọ gbogbo ara kiki ọrọ. Awon ti wọn n pe mi bẹẹ ni wọn mọ ohun ti wọn ri, ṣugbọn mi o fun ara mi lorukọ ri, Ọlọrun lo mọ bo ṣe da mi.  Ọrọ ẹnu ni mo n ta ninu fiimu, ti mi o ba sọ bẹẹ wọn ko ni i lo mi fun ere, ọrọ ni mo n jẹ, ṣugbọn loju aye, ki i ṣe bi mo ṣe ri niyẹn

Ẹyin ni aarẹ ẹgbẹ ANTP, ki lẹ ri tẹ ẹ fi joye yii?

 

Eeyan gbọdọ mọ ohun to fẹẹ ṣe ati ilọsiwaju to fẹẹ mu ba ẹgbẹ atawọn ọmọ ẹgbẹ. Nitori ki idagbasoke ati ilọsiwaju le ba ẹgbẹ ati awọn ọmọ ẹgbẹ lo gbe mi de idi ipo aarẹ ẹgbẹ ANTP.

Ọkan ninu awọn gbajumọ apanilẹrin-in lori ẹrọ ayelujara ni ọkan ninu awọn ọmọ yii, iyẹn Yẹmi Ẹlẹsọọ ti wọn n pe ni Bọọda Nuru . Bawo lo ṣe ri lara yin nigba ti ẹ n gbọ orukọ ẹ?

Ohun ti mo kọkọ sọ fun un ni pe o gbọdọ kawe jade ni yunifasiti, o si gbọ ohun ti mo sọ fun un. Mo sọ fun un ni pe lẹnu igba to ti kawe, Ọlọrun yoo fi alubarika si i.

Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun pe ko ba mi loju jẹ, bi mo ṣe n gbọ orukọ ẹ kaakiri o maa n dun  mọ mi ninu. Nigba ti mo lọ si Amẹrika, awọn ololufẹ ẹ ni wọn waa fi mọto gbe mi, ti wọn ṣe daadaa fun mi. Mo dupẹ o, oriiire rẹ ko ni i taku sibi to e, gbogbo ohun rere to n fẹ ni Ọlọrun yoo ṣe fun un.

Ẹyin ni aarẹ ẹgbẹ ANTP, Mr. Latin ni aarẹ ẹgbẹ TAMPAN. Bawo ni ajọṣepọ yin?

Ti wọn ba n darukọ aṣaaju daadaa ati ọmọluabi eeyan, Mr. Latin ni wọn n sọ, bibire ko ṣe e fowo ra.Ko sija laarin emi ati ẹ, mo ṣere pẹlu awọn TAMPAN. Ẹgbẹ wa lo yatọ, iṣẹ kan naa la jọ n ṣe, ọpọ igba ni Mr.Latin ma n pe mi sakiyesi ohun to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ mi. Awọn ti wọn n ba ara wọn ja nitori ẹgbẹ ni ko mọ ohun to n ṣe wọn

No comments:

Post a Comment

Adbox