Inu idunnu ati ayo nla lawon obi omo odun mewaa kan, Adams Mustapha wa bayii, ko si ohun to fa ayo ati idunnu ohun ju bi omo won se soriire lori eto sebilu Nnjat Concept, ti gbajugbaja aafaa oniwaasi nni, Sheikh Alhaji Olanrewaju Ahmad Alfulanny je agbateru.
Eto yii to ma n waye lori telifisan WAP TV ati ikanna ero ayelujaja Facebook lasiko aawe ramadan ti a wa yii ni Adams ti je ebun meka, owo tiye re je milionu kan aabo o le die, ile pulooti kan ati ebun repete. Gbogbo ibeere merin ti won beere lowo omodekunrin yii to pe wole sori eto lati ilu Ikorodu lo gba patapata.
Yato si awon ebun ti a daruko yii, won tun fun omo yii lebun eko-ofe fun eeyan mewaa. Lara awon eeyan ti won fun omo yii lowo to po ni: Alaga awon onimoto nipinle Eko, Alhaji Musiliu Ayinde Akinsanya MC Oluomo, Alhaji Rasheed Adeleke Agba Owo atawon mi-in.
No comments:
Post a Comment