Taofik Afọlabi
Ọkan ninu awọn aafaa nla nipinlẹ Eko ni Fadhilat Sheik Abdulwaheed Balogun Olu-Love, ọkunrin naa ni oludasilẹ ijọ alasaalatu ti orukọ n jẹ ‘Alahu Fatihu Mujeeb Islamic Prayer’ to wa ni Ikorodu. Laipẹ yii ni aafaa naa ba wa sọrọ. Diẹ ninu ohun ti wọn ba wa sọ ree.
Orukọ mi ni Fadhilat Sheik Abdulwaheed Balogun Olu-Love, emi ni oludasilẹ ijọ, Alahu Fathu Mujeeb Islamic Prayer Group Internatinonal to wa ni ilu, Ikorodu, niluu Eko. Gbogbo ẹni ti Ọlọrun ba ni ko wa si ọdọ wa, a sọ ohun ti yoo ṣe fun ti gbogbo ohun ti oun beere fun yoo to o lọwọ. Ohun to jẹ ka gbe ijọ wa kalẹ ni lati fi tu gbogbo eeyan silẹ ninu iṣoro nipasẹ adura.
Ko si ẹni to tẹri wọ inu ijọ wa ti bukaata rẹ ko ni i biya, o ti le ni ọdun mẹẹẹdogun ti Ọlọrun ti gbe ijọ yii kalẹ, lati igba naa Ọlọrun n ti ọwọ wa ṣe awọn ohun meremere ti a ko lee fẹnu sọ tan. Ọpọ awọn eeyan ni Ọlọrun ti ti ara wa ṣe oore nla fun. Ohun ti mo ma n sọ fun awọn eeyan ni pe iwọ maa bọ pẹlu igbagbọ pe iṣoro rẹ yoo biya, nitori pe ọba to ni mi, o ga ju gbogbo iṣoro wa lọ.
Lara awọn iṣẹ rere ati iṣẹ iyanu ti Ọlọrun ti ti ọwọ wa ṣe ni ti ọkunrin kan to sanwo masinni si ilu oyinbpo, lẹyin bii osu mẹfa ti o ti sanwo masinni yii ko ri masinni, Ọlọrun si sọ pe ko wa si ijọ wa, bo ṣe de ni a sọ isoro to n la kọja fun lori masinni ẹ to n reti yii, o ni bẹẹ ni, o ni kin ni a le ba oun ṣe si i, mo beere lọwọ ẹ pe ṣe o ni igbagbọ, o ni bẹẹ ni, ẹni yii ko denu ijọ wa ri, ọkan ninu awọn ọmọ ijọ wa to ri lọna lo te le wa si asalaatu wa lọjọ naa. Ẹni ti mo n sọ yii ki i ṣe Yoruba, Edo ni. Lojuẹsẹ ni mo ni ki awọn alasalaatu ẹ ka bẹrẹ adura fun un, bẹẹ ni mo sọ fun un pe ko lọọ ṣe saara, lẹyin ọsẹ meji lo pe mi pe masinni oun ti de.
Bẹẹ ni obinrin kan to wa si asalaatu wa, lọjọ to wa ni mo sọ fun un pe ọmọ mẹta lo ti ku mọ ọn lọwọ, mo sọ fun un lọjọ naa pe lọjọ igbeyawo ni wọn ti fi idaamu bibi oku ọmọ ṣe adanwo fun un, naira mẹwaa ti wọn lẹ mọ ọn lori lọjọ igbeyawo ẹ ni wọn ṣe iṣe aburu yii si. A ṣe adura fun un, mo si sọ fun un pe yoo loyun, yoo si bimọ ti ko si ni i bi abiku mọ laye, o ti bimọ mẹta bayii.
Bẹẹ la ni eto adura kan ti a maa n ṣe lẹẹkan lọdun ti gbogbo eeyan maa n wa kaakiri agbaaye, ọpọ ẹri lo n ṣẹlẹ ninu eto adura yii nitori ko si ẹni ti to wa ti ko ni i ri tiẹ ṣe nibẹ. Omi ni a n lo lati fi tu awọn eeyan silẹ nibi eto adura yii.
Ẹ le pe Sheik Olu-Love sori nọmba yii: 08028272844 tabi 08092987073
No comments:
Post a Comment