Gọngọ yoo sọ lọjọ lọjọ kejidinlọgbọn oṣu yii ninu gbọgan 'Times Square Event Centre, to wa Ikeja. Ọjọ naa ni ọga awọn olorin Islam lorilẹ-ede yii, Alaaji Wasiu Kayọde As-Sideeq tawọn eeyan mọ si Baba-waka, yoo ṣayẹyẹ onibẹta lọjọ kan ṣoṣo. Ayẹyẹ ọhun ọgbọn ọdun to ti n kọrin, fifun awọn musulumi ododo ọgbọn lami-ẹyẹ ati ikojade fidio rẹkọọdu ẹ to pe ni ‘Ẹ samin’ ati rẹkọọdu tuntun ti wọn sọ orukọ ẹ ni ‘ Iwa la n wa’.
Baba ọjọ naa ni olori ile igbimọ aṣofin Eko, Ọnarebu Mudathir Ajayi Ọbasa, alaga ọjọ naa ni Hadji Yusuf Ayinla Anobi Musin, nigba ti mama ọjọ naa yoo jẹ Alaaja Tawakalitu Muse Balogun. Awọn alaye ọjọ naa ni Ọba Abdulfattah Akorede Akamọ Olu tilu Itori ati Ọba Muhammad Saheed Ifalohun Onidioke tilu Igbẹsa. Alejo Pataki ọjọ naa ni Alaaji Abdul Ganeey Oluṣẹgun Awokọya.
Awọn oṣere ti wọn reti nibi ayẹyẹ naa ni: Alaaji Sẹfiu Alao Baba Oko, Alaaji Sule Alao Adekunle Malaika, Alaaji Wasiu Alabi Pasuma, Alaaji Saheed Oṣupa Akorede, Alaaji Abass Akande Obesere, Madam Saje, Ọga Bello, Saidi Balogun, Okunnu, Lawori, Ibraheem Chatta, Ọlaiya Igwe, Jagaban, Eko, Ayinla 220 atawọn olorin Islam
No comments:
Post a Comment