Igbagbo gbogbo awon to feran lati ma a wo fiimu agbelewo ni pe ololufe ni awon osere wa meji nni, Lateef Adedimeji ati Mobimpe.
Asiko kan wa ti ariwo gba ori ero ayelujara pe awon osere naa segbeyawo alarede.
Ko si ohun to fa a ju bi awon mejeeji se n maa n se bii toko-tiyawo lori ero alatagba ati awon foto ife ti awon eeyan naa n ju sita lo
Sugbon, Lateef ti soju abe nikoo, omokurin naa ti so pe Mobimpe ki i se ololufe oun rara, o ni ipolowo lasan lawon n fi awon foto naa se fawon ileese nla nla, ti owo si n wole sawon lapo.
Nibi oko ere, Ayinla ti won ya niluu Abeokuta, nipinle Ogun ni Lateef ti tu asiiri naa fawon telifisan Alaroye.
Ju gbogbo e lo, Lateef ti ni akegbe oun lasan ni Mobimpe lagboole tiara, ki i se ololufe oun rara.
No comments:
Post a Comment