Ebi Oniwonlu, okan lara awon ebi to n jo ba niluu Ibeji Agbe, ni Ibeju-lekki ti rawo ebe si gomina ipinle Eko, Babatunde Olusola Sanwo-Olu pe ko ba awon da si oro Onibeju tuntun ti won fee yan naa.
Lasiko to n ba oniroyin wa soro, Olori Alaagba, to tun je okan ninu awon omo igbinmo to yan awon to dije lati dunpo Onibeju, Oloye Sikiru Adediran, lo ti so pe awon afobaje ti Oloye Moshood Adewale Aro je olori won fee fi tipatipa fa eni ti oye ko to si le awon araalu lori.
Adediran ni igbese akoko ti ebi Oniwonlu gbe ni pe awon pe gbogbo awon omo ebi naa pe eni to ba nifee si ipo Onibeju ki won waa gba foomu. Awon mokandinlogun ni Adediran so pe won jade lati dunpo, tawon ko gbogbo won lo si oju ishi nibi tawon ti so fun pe eni ti ipo naa ko ba ja mo lowo pe ko gbodo lo si kootu tabi fi olopaa hale mo alatako e.
O ni awon ya fidio ibura awon oludije yii, o ni leyin e lawon mu oruko awon oludije yii lo si oko ifa, sugbon awon meta pere ni ifa mu. Awon meta ohun ni:Idris Ajumobi Oniwonlu, Adewale Abdulwasiu Oniwonlu ati Ademuyiwa Akande Oniwonlu.
Okunrin yii ni kayeefi lo je fawon nigba ti iroyin kan awon lara pe olori adobaje fee gbe okunrin kan ti oruko e n je Waliu Rasak Olasunkan le gbogbo ilu lori gege bii Onibeju tuntun.
O ni eni ti Oloye Aro gbe wa yii ki I se omo ebi Oniwonlu, o ni Idris Ajumobi Oniwonlu lawon fe, oun si ni ifa re kun ju ninu awon meta ti ifa mu at I ebi Oniwonlu lo kan lati je Onibeju tuntun
O fi kun oro e re pe Waliu ti Oloye Aro mu wa yii ko si ninu awon meta ti ifa mu. Adediran ni awon Oba to waja, iyen, Oba Rafiu Oluwasegun ati Oba Musa Agbabiiaka lati ebi Abejoye ati Aladeseso ni won ti wa, idi lo se je pe ebi Oniwonlu loba to si bayii.
O lawon ti ko leta si gomina, komisanna, adajo agba ipinle Eko ati ileese to n ri si oro oba jije nipinle Eko lati fi igbese ti awon afobaje yii n gbe to won leti.
O wa a be gomina lati ba awon da si oro naa, ko ma di ohun ti yoo da wahala sile niluu Ibeju.
No comments:
Post a Comment