IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Friday, 22 January 2021

Asiiri iku to pa Tajudeen Ishola Onifuji ree

Ojutole lo koko kede iku agba-oje olorin fuji nni, Alaaji Tajudeen Ishola tawon eeyan mo si Ashanty Sholay fun yin.

Ohun ti a gbo nipa iku osere to maa n saaba kolu Wasiu Ayinde lori ero ayelujara ni pe lati inu odu kokanla odun to koja lokunrin naa ti wa lori idubule aisan. Ariwo inu rirun lo pa tawon eeyan fi gbe e digbadigba lo si ileewosan, sugbon awon dokita ko ri nnkan toka si pe o run un ninu.

Enu e ni won wa ti okunrin naa fi dake.
Okan ninu awon olorin fuji to dide lati Isale-Eko nibere odun 1990 lokunrin naa, oun Wasiu Ayinde, Musibau Alani, Toyin Adio ni won n Jo n ba ara won fa a ko too lo siluu France to dake si yii.

Ki Olorun se iku nisinmi fun Ashanty Sholay.

No comments:

Post a Comment

Adbox