Beeyan ba jẹ
ori ahun omi yoo bọ loju ẹ to ba debi ti ibọn awọn asọbode, ti wọn pe
ni kọsitọọmu ti yinpa pa ọdọmọkunrin, ẹni ọdun mẹẹẹdogun kan ti wọn pe orukọ ẹ ni
Riliwan Bello.
Gẹgẹ bi a ṣe
gbọ, laarọ ọjọ Ẹti, Fraide to kọja ni wọn iṣẹlẹ naa waye ni garaaji Owode-
Idiroko.Ọmọleewe girama 'Area Community High School to wa ni Owode ni wọn pe, bakan naa ni wọn sọ pe kilaasi giga akọkọ SS1 lo wa nileewe girama
Iwadii fi ye wa
pe ṣe lawọn asọbode yawọ garaaji Owode, ti wọn ni wọn bẹrẹ si ni fọ ṣọọbu, ti
wọn si n ko apo ṣuga jade, bẹẹ ni wọn sọ pe wọn tun yinbọn soke lati fi le awọn
eeyan.
Ara ọta ibọn
ti wọn sọ pe wọn yin soke yii lo ba Riliwan lori, ti ori ẹ si fọn ka, to si
ku loju ẹsẹ, gbogbo akitiyan awọn to wa nibi iṣẹle ọhun lati doola ẹmi ẹ lo
ja si pabo.
Gbogbo akitiyan wa lati gbọ tẹnu awọn aṣọbode lori iṣẹlẹ yii lo ja si pabo
nitori bi agbẹnusọ wọn, Malwaida ṣe sọ pe oun yoo pe wa ṣugbọn ti ko pe pada
titi taa fi n kọ iroyin yii.
No comments:
Post a Comment