IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Monday, 9 March 2020

Gbajumo olorin Islam, Ummu Niyas fee sayeye nla l'Ekoo


Okan pataki ninu awon gbajumo olorin Islam lorile-ede yii ni  Hajia Aishat Adeleke ti gbogbo aye mo si Ummu Niyas, obinrin naa fee sayeye nla lojo kejila osu kerin odun ti a wa yii. 
 
Ayeye ohun ni ogun odun to ti n korin, ifilole ileewe ti won ti n ko nipa orin ati fifun awon eeyan kan lami-eye.Gbongan  'Combo Hall', to wa ninu ogba ileese telifisan LTV to wa ni Ikeja layeye naa yoo ti waye. 
 
Lasiko to n ba wa soro, Ummu Niyas so pe ojo naa yoo larinrin pupo, o ni gbogbo awon eeyan to ba wa sibe ni won yoo gbadun ara won daadaa. Awon olorin atawon eeyan pataki lawujo ni won reti nibi ayeye naa.
 
Aso tawon eeyan yoo fi wole ni : Ankara opa mefa ati gele egberun mejo naira,  ankara opa merin ati gele egberun mefa naira, leesi egberun meeedogun naira ati  Atiku egberun mewaa naira. Fun alaye



lekunrere, e pe nomba yii: 09056505608 or 09015162078

No comments:

Post a Comment

Adbox