Lara ẹsun ti Oloye Ogedengbe fi
kan Ọwa ni pe ọba naa ma n lo awọn ọmọọta ti wọn n pe ni tọọgi lati fi dunkoko
mọ awọn ẹnikẹni to ba fẹẹ kọ ile ni Ileṣa, eyi to ma n fa wahala ni gbogbo
igba, eyi si n da omi alaafia ilu naa ru.
Ẹsun mi-in ti Oloye Ogedegbe fi
kan Ọwa ni pe owo nla ti Kabiyeesi beere lasiko ti wọn fẹẹ ṣe omi ẹrọ siluu, o ni Kabiyeesi yari pe wọn ko
gbọdọ ri ẹrọ omi naa, wọn ko si ri i ṣe di bii a ṣe n sọrọ yii. Bakan naa la
gbọ pe Ọba Alaye yii leri pe oun ju ijọba lọ ati pe ko si ohun ti ẹnikẹni to le
da oun lọwọ ko ohun ti oun ba fẹẹ ṣe.
Ọba nla waa rawọ ẹbẹ si ijọba
ipinlẹ Ọsun lati ba awọn da si wahala ti Ọwa n da silẹ laarin ilu yii, ki
wahala ma di ohun ti apa awọn agbofinro ko ni i ka.
Gbogbo akitiyan lati gbọ ọrọ lẹnu
Ọwa lo ja si pabo, agbẹnusọ wọn ti a ba sọrọ, Alagba Ọlatunbọsun sọ pe Kabiyeesi ko ti i da gbogbo
ibeere ti a bi wọn.
No comments:
Post a Comment