Gbogbo awọn
olorin fuji pata lorilẹ-ede Amẹrika, London ati ni Naijiria ni wọn ṣedaro ọkan
ninu wọn Tọpẹ Aṣakẹ Makanaki to jade laye.
Nibi adura ọjọ mẹjọ ti wọn se fun obinrin naa
lawọn onifuji lorile-ede Amẹrika ti Ambasadọ Adewale Alamu jẹ aarẹ wọn ti fowo
nla ranṣẹ si awọn ọmọ ti Oloogbe naa fi saye lọ. Bakan naa la gbọ pe awọn olorin fuji ni London ti Alaaji Ayinla
Forsure naa jẹ aarẹ wọn naa fowo ranṣẹ si awọn ọmọ Tọpẹ Makanaki.
Gbogbo
awọn ọmọ ẹgbẹ FUMAN ni Mushin lo peju- pesẹ sibi adura ọjọ mẹjọ obinrin olorin
fuji naa to waye loni-in. Lara awon ti a
gbo pe won wa nibe ni: Sule Ajani, , Alhaja Musiliat Arike, Alhaja Amudalat Awẹni
Oniwaka, Alaaji Kamoru Gbogeraye atawọn
mi-in. Alhaji Abiodun Ejire Patira to jẹ
akapo ẹgbẹ FUMAN lorile-ede yii lo ṣoju awọn ẹgbẹ olorin fuji lorile-ede yii
nibi adura naa.
Ninu ọrọ awọn Fuman
ti Mushin ti Tọpẹ Makanaki ti jade nu wọn ti dupe lọwọ awọn ẹgbẹ olorin nipinlẹ Eko ati gbogbo
ọmọ ẹgbẹ pata . Wọn gbadura pe gbogbo wa ko ni i foju sunkun ara wa.
No comments:
Post a Comment