IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Saturday, 21 December 2019

SAIDI OṢUPA FẸẸ ṢERE ỌDUN FUN ỌNAREBU AJIFAT

Ọnarebu Fatai Ajidagba Ajifat
Gọngọ yoo sọ lọjọ kọkandinlọgbọn oṣu yii, ọjọ naa ni gbajugbaja olorin fuji, Alaaji Saheed Oṣupa Akorede yoo ṣere ọdun fun alaga  ijọba idagbasoke ibilẹ Ajerọmi Ifẹlodun, Ọnarebu Shuaibu Fatai Ajidagba ti gbogbo aye mọ si Ajifat. Inu ọgba awọn ologun, iyẹn Signals Barack to wa ni Alaba-Suru layẹyẹ nla yoo ti waye.

Ilu mọ ọn ka sọrọsọrọ ori radio ati tẹlifiṣan nni, Ambasandọ Yọmi Matẹ tawọn eeyan mọ si Ifa-n-kaleluyah ni yoo dari ayẹyẹ naa. 

Ojutole gbọ pe gbogbo eto bi ariya ọdun naa to maa n waye lọdọọdun yoo ṣe larinrin daadaa ni Ọnarebu Ajidagba

ti ṣe. Awọn eeyan pataki lawujọ la gbọ pe wọn n bọ nibi ayẹyẹ ọdun yii.      

No comments:

Post a Comment

Adbox