Ọjọ nla lọjọ
Aiku, Sannde to kọja lọhun-un fun gbogbo ẹbi Adoyi Ifadu Alashẹ nipinlẹ Eko,
idi ni pe ọjọ naa ni gbogbo ẹbi panupọ ti wọn sọ pe ọkunrin oniṣowo pataki to
fi ilu Eko ṣebugbe, Ọmọọba Akeem Idowu Olomitutu lawọn fọwọ si pe ko jẹ ọba ilu
Oke-Alọ ni Gbagada.
Olori ẹbi naa,
Oloye Rasak Eshinlokun lo fa ọwọ ọkunrin naa soke niwaju gbogbo ẹbi, ti gbogbo
wọn si pariwo pe Olomitutu lawọn fẹ nipo ọba ilu yii. Ohun tawọn ẹbi sọ ni pe ẹnikan
ṣoṣo ti gbogbo awọn fọwọsi, ti awọn nigbagbọ ninu ẹ ni Olomitutu, adura wọn si
ni pe kijọba gba oun tawọn fẹ yii wọle.
Ninu ọrọ Oloye
Eshinlokun lo ti sọ pe awọn ti ṣayẹwo fun Olomitutu daadaa, bẹẹ lawọn mọ pe
olododo eniyan to fẹran gbogbo ẹbi ni lo jẹ kawọn sọ pe oun gan-an lawọn fẹ
nipo ọba yii. Baba yii ni ohun ti awọn duro bayii ni kijọba fowọ si ẹni tawọn
eeyan yii, nitori pe awọn nigbagbọ ninu ẹ pe ọpọ anfaani ati idagbasoke ni Ọlomitutu
yoo mu b awọn to ba depo ọba.
Lasiko to n sọrọ
nibi ipade nla ti wọn ti yan an yii, Ọlomitutu, loun dupẹ lọwọ gbogbo ẹbi fun
bi wọn ṣe yan oun gẹgẹ bii ọba yii, o loun ko ni i ja wọn kulẹ rara. Bẹẹ lo rọ
pe ki wọn tunbo maa ṣatilẹyin foun nitori pe oun ko le e da a ṣe. Olomitutu ni ọpọ
idagbasoke ni yoo wọ ilu toun ba dori aleefa awọn baba nla oun.
No comments:
Post a Comment