IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Saturday, 21 December 2019

ILEESE YAFADOT Group of companies BERE IPATE OJA NI ALAUSA

Lati ojo Eti, Fraide, ana ni ileese Yefadot Group of companies  labe alase ati oludari e, Oloye Yetunde Babajide ti gbogbo aye mo si Yefadot ti bere ipate oja ti won maa n se lodoodun. Eni to ba wa inu ileese ijoba ipinle Eko to wa ni Alausa yoo mo pe nnkan nla ti n sele nibe. Pitimu lawon oloja, awon olounje atawon  onise-owo kun iwaju gbongan Adeyemi Bero ti oja ita gbangba ohun ti waye. Odidi ojo mefa la gbo pe won yoo fi na oja yii, ko si ohun ti eeyan n wa ti ko ni i ri nibe,paapaa awon nnkan ti enu n je.

Lasiko ti Oloye Babajide, to tun je aare egbe Agbeloba n ba Ojutole soro lo ti so gbogbo awon agbe tawon je aladani lawon gbe ipate oja yii kale. O ni akori ipate oja ohun lawon pe ni 'E je ka je ohun ti a n gbin, ka gbin ohun ti a n je, ka wo ohun ti a n se, ka se ohun ti a n wo. Iyalode ilu Ojodu ni gbogbo ohun jije ati ohun lilo ara ni won ko wa sibi ipate oja naa lo je ohun ti awon se yii. Lara awon ounje tawon eeyan yoo ri ra lowo pooku nibi ipate oja yii ni: elubo, raisi, ewa, gaari, isu, epo, iru, ata ati gbogbo ohun ti enu n je. O ni awon onisegun ibile paapaa wa nibi ipate yii. Bee lo so pe awon ti se iwosan ofe lori ito suga ati ifunpa fun awon eeyan, bee lo so pe emu funfun, agbon, oro, eyin, elubo ogede tun wa nibi ipate oja yii.

Bakan naa lo so pe ileese ijoba to n ri si eto ogbin ati ise naa wa pelu awon nibi ipate yii. Iyalode ni gbogbo oja tawon n ta lawon ti yo ida ogun kuro nibe ko le ro awon eeyan lorun lati ra. Bee lo so pe idi tawon fi gbe oja alagbeeka yii kale ni lati fi ro awon ti ko lowo lati gba soobu lowo.   O tun te siwaju si i pe awon yoo tun ko awon eeyan nise owo nibi ipate yii, bee lo so pe eto eyawo wa nibi ipate oja yii. O wa a ro gbogbo awon araalu lati wa janfaani nla tawon gbe kale yii.             

No comments:

Post a Comment

Adbox