Gbogbo awọn
eeyan to wa nibi adura ọjọ kẹjọ ti wọn ṣe fun Alaaja Falilat Ọrẹdọla Giwa to
waye ninu papa iṣere ‘Agege Stadium’ ni wọn sọ pe aye yẹ ẹ mama yii, bẹẹ ni
ẹyin ẹ naa dara, pẹluu bi awọn eeyan pataki lawujọ, awọn ọmọwe atawọn aafaa nla
ṣe peju-pesẹ sibi adura yii.
Ọkan ninu awọn
ọmọ mama yii, Alaaja Ramotalahi, ti i ṣe iyawo agba aafaa nla nni, Sheik Faruq
Onikijipa lo sagbateru adura yii fun mama ẹ to ku yii. Sheik nla nni, Sheik
Habibulahi Al-Ilory lo se adura ati waasi pataki nibi eto adura ọjọ kẹjọ yii.
Ẹni to ba ri
Sheik Onigijipa lọjọ naa yoo mọ pe aafaa nla yii soju, bẹẹe lo seyin rere fun
ana ẹ yii. Leesi funfun balau ni Alaaja Ramotalahi atawọn ọmọ olooku wọ lọjọ
yii. Lara awọn alejo pataki ti wọn wa nibi adura yii ni: Timi tilu Ẹdẹ, Ọba
Muniru Laminisa atawọn olori wọn, Sheik
Bọla Belgore, Ọnarebu Sulaimọ Abubakar, Alaaji Tajudeen Usamot, Sheik Akosile, Sheik Abdulahi Akinbọde,
SheikSaobana Al-Ilory, Sheik Faruq,
Imaamu ilu Agege, Alaaji Moshood Alebiiosu atawọn eeyan jankanjankan mi-in
lawujọ
No comments:
Post a Comment