IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Saturday, 23 November 2019

TOYIN AGBOLADE, AKOROYIN IWE IROYIN ALARIYA OODUA, SAYEYE OJOOBI PELU AWON OMO ALAINIYAA

Ojo nla ti okan pataki ninu awon akoroyin ileese iwe iroyin Alariya Oodua, to tun je olootu fun abala awon obinrin, Oluwatoyin Agbolade, ko le e gbagbe boro lojo Eti, Fraide, ana yii. Ojo naa lomobinrin naa sayeye ojoobi e. Sugbon Toyin se kinni kan dipo ko gbe ayeye ojoobi yii lo sile ijo, ile awon omo alainiyaa iyen, 'Ijamido Motherless Home' to wa ni Sango, nipinle Ogun ni Toyin  gbe ayeye yii lo, nibi to ti febun nla ta awon omo yii lore.

Ninu oro e lo  ti so pe inu oun dun, ayo oun si kun pe ojo yii ba oun laye, o ni oun dupe lowo Olorun pe oun le ojo kan si i loke eepe.



Toyin ni 'E ba mi dupe lowo Alaaji Akewusola ni Idiroko atawon  oga mi woyii: Kunle Babarinde Taofik Afolabi,  Ambasando Yomi Mate Ifankaleluyah, Oloye Abiodun Adeoye Afefe-Oro, Wale Omotola, Yeye Bidemi Olukuewu ati Sina Adegbite

No comments:

Post a Comment

Adbox