IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Friday, 15 November 2019

OBA ORIN JUJU-MILIKI, DELE GOLD, FORIN DABIRA NIBI ISOJI IDANDE TO WAYE NI SANGO

Ojo nla ti awon Sango-Ota ko ni i gbagbe boro lojo ti gbajumo olorin emi nni, Ambasando Dele Agbeyo ti gbogbo aye mo si Dele Gold korin ni isoji idande ti Wolii Agbaaye nni, Prophet Sam Ojo gbe kale.



Se lo dabii eni pe awon angeeli so kale nigba ti Dele Gold n korin, se ni inu gbogbo obitibiti awon eeyan to wa nibe n du sawon orin imisi ati idande to n jade lenu oba orin juju miliki yii.

NIbi tawon eeyan gba ti gbajumo olorin yii de, won ko fe ko da enu duro mo lojo yii, won lawon gbadun awon orin aladun to ju sile fun awon. Ohun to sele yii, lo je kawon ojise Olorun ti Prophet Sam Ojo saaju won rojo adura fun Dele Gold leyin to korin tan.

No comments:

Post a Comment

Adbox