IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Tuesday, 12 November 2019

OJO NLA LOJO TI ALAAJI YUNUS OLAJIDE ONI JOYE SERIKI ADINNI MOSALAASI NLA OLORUNSOGO NI KETU,GBOGBO AYE LO PEJU SIBE





























Ojo nla ti yoo pe e daadaa ki gbogbo awon ara Ketu, nipinle Eko atawon agbegbe e too gbagbe boro lojo Aiku, Sannde to koja yii. Ojo nla naa ni won fi Alaaji Oloye Yunus Olajide joye Seriki Adinni gbogbo mosalaasi nla Olorunsogo Central Mosque to wa ni Ketu.

Bii omi lawon eeyan ri ninu gbongan nla ti ayeye naa ti waye, akobi  baba oloye tuntun naa, Alaaja Olabisi  Fausiyah Edu, lo sagbateru ayeye nla ohun fun baba e, obinrin yii ri i pe gbogbo awon eeyan ti won wa sibi ayeye yii ni won je, ti won mu,ti won tun di lo sile.

Bo ti le je pe ki i se baba yii nikan lo joye lojo yii,sugbon ojo naa ye e daadaa, gbogbo awon eeyan to wa nibe ni won so pe Alaaji Yunus bi awon omo alalubarika.

Lara awon eeyan pataki ti won wa nibe ni: Senator Musiliu Obanikoro,  Onarebu Ajala, Sheik Omooba Babatunde Sulaimon al-Internety,Onarebu Yemi Alli atawon eeyan jankan-jankan mi-in lawujo. Imaamu agba ilu Ofa lo se waasi lojo naa.

Kinni kan to tun je ki ariya yii larinrin ni pe, gbogbo awon ore Alaaja Fausiyah ni won peju-pese sibi ayeye yii nitori ore won.     
Awon gbajugbaja olorin Islam meji nni, Alaaja Bashirat Ogunremi ti gbogbo aye mo si Iya-n-Ghana ati Addish Nigga ni won korin nibi ayeye yii.





































No comments:

Post a Comment

Adbox