IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Thursday, 24 October 2019

Gbajumo ajafetoo, Rasaq Olokoba gboriyin fun Sanwo-Olu, o ni okunrin naa ti mu ileri to se fawon ara Eko se

Ogbontarigi ajafetoo omo eniyan ati aare egbe ‘Campaign for Dignity in Governance (CDG), Komuredi  Razaq Olokoba, ti gbe osuba o kare laye fun gomina ipinle Eko, Ogbeni  Babajide Olusola Sanwo-Olu  fun bo se n mu awon ileri to se fawon ara Eko lasiko ipolongo e se. Image may contain: 1 person, sitting 

Olokoba,  ninu atejade to fi sowo si wa lo ti so pe igbese nla ati akin ni Sanwo-Olu gbe nipase bo se kede atunse kiakia sawon ojuona to ti baje nipinle Eko ati sisan egberun lona ogbon naira gege bii owo osu osise to kere ju fawon osise. O  fi kun oro re pe oun ti Sanwo-Olu se yii fihan pe eni to ye nipo lawon ara Eko dibo yan gege bii gomina won.  

Ogbontarigi ajafetoo omo eniyan yii fi kun oro e pe bi ipinle Eko se je ipinle ti pupo ninu oro aje orile-ede yii ti n wole, o ye kiru ipinle bee ni ojuona moto to dara, to se e rin fawon oko, ti ko si ni I si sunkere-fakere oko lati di lilo bibo oko lowo.  

O ni pelu ohun ti Sanwo-Olu se yii, o ye kawon eeyan fowosowopo pelu gomina lati tunbo gbe ipinle Eko ga ju bo se ye lo. O tesiwaju pe ninu oro e pe bi Sanwo-Olu ba n se bo se n yii, ohun to daju nip e laarin odun kan ilu Eko yoo lo siwaju si I, sugbon a tun gbodo maa sin in ni gbere ipako ti yoo fi se ju eyi to n se yii lo di idagbasoke otun yoo fib a ipinle Eko
 

No comments:

Post a Comment

Adbox