IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Thursday, 3 October 2019

Agba-oje osere tiata Yoruba, Ayoka Ologede fee sayeye nla fawon okola l’Ekoo

Fun igba akoko lorile-ede yii, tabi ka so pe lagbaaye, agba-oje osere tiata Yoruba nni, Emmanuel Ayandotun tawon eeyan mo si Ayoka Ologede fee sayeye nla fun awon to kola.      
Ayeye ohun ti won pe ni Okola Day ni yoo waye lojo ketala, osu kewaa, odun yii ni gbongan Time Square Event to wa ni Adeniyi Jones, nipinle Eko. Oga Nla awon onifuji, Alaaji Wasiu Alabi Odetola Pasuma ni yoo korin lojo naa, nigba ti Muyiwa Adegoke Londoner ati Tunde Usman ti won tun n pe ni Okele tawon naa kola yoo je adari ayeye yii.
Lasiko to n wa soro nipa ayeye yii, Ayoka Ologede ni iru e ko sele lorile-ede yii, o ni oun gbe ayeye naa kale lati fi se koriya fun awon eeyan ti won kola. Ayoka ni oju eni ti ko laju tabi ara oko lawon eeyan paapaa, awon ara Eko fi maa n wo awon to kola, eyi tawon eeyan naa fi ri ila kiko bii adanwo tabi aleebu ara.
O loun fee lo ayeye naa lati kawon eeyan mo pe ila kiko ki I se aarun tabi ori buruku. Alejo Pataki ojo naa ni Alaaji Rasak Adeleke ti won tun n pe ni Agbaowo.  

No comments:

Post a Comment

Adbox