IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Saturday, 20 April 2019

EGBE AWON ONIFUJI L'AMERIKA,FUMAA KI JENERA KOLLIGHTON AYINLA KAABO S'AMERIKA

Egbe awon onifuji lorile-ede Amerika,iyen Fuji Musicians Association of America (FUMAA)  ti ki baba awon onifuji lorile-ede yii, Alaaji Jenera Kolligton Ayinla kaabo sorile-ede Amerika. Egbe yii ti won sese da sile ti Mayor  Akeem Alamu je aare won ni ti so pe inu awon dun gidigidi lati gbalejo baba awon onifuji yii lorile-ede Amerika.

Ojutole gbo pe ni gbogbo awon onifuji ti won n gbe lorile-ede Amerika panupo lati da egbe yii sile. Lasiko ipade awon akoko ni won yan Mayor Akeem Alamu to ti figba kan je akowe egbe FUMAN nipinle Eko gege bii aare egbe naa, ti won si yan Wale Yosiyo gege bii akowe egbe titi digba ti won yoo seto idibo lati yan awon oloye egbe..

Awon omo egbe yooku ni: Alhaja Muinat Ejide, Suufi Aloma, Ibrahim Awoko, Alh Akeem Tutuye,  Taofeek Igisekele,  Adewale Barry showkey, Adekunle Augustine,  Akande Yinusa, Bashiru Ajao, Mr. sugar, Omo Yeye Akata toh ko Fuji, Sarafa Iyanda  ati  Safejo Amama.

No comments:

Post a Comment

Adbox