Bi e se n ka iroyin yii, ayeye nla ti bere lori ayeye odun kewaa ti won da ileese eleran igbalode toruko e n je 'Meat Embassy' sile.
Lasiko
ti oga ileese naa, Ogbeni Babatunde Samuel Wilkey ba awon oniroyin soro lopin ose to koja yii lo ti so pe ojo
karun-un, osu yii layeye naa ti bere, ti asekagba re yoo waye lojo
kejila osu yii kan naa.
Lara awon eto ti won la kale
fun ayeye yii sisabewo sodo awon omo alainiyaa, nibi ti won yoo ti febun
nla tawon lore, tinu awon naa yoo dun lojo yii.
Bakan naa
lawon onibaara ileese yii yoo janfaani ebun repete, bee lawon osise ti
won mu ise won ni koko naa yoo gba ebun ati ami-eye lo sile lasiko ayeye
yii.
Ojo kejila yii niweje-wemu yoo waye, ojo naa lawon olorin olokan-o-jo-kan yoo forin aladun da awon eeyan lara ya.
Ogbeni Babatunde fi kun oro re pe oga-agba ileegbafe 'African Continent World-Wide Hotel' ni yoo seidanilekoo fawon eeyan lojo naa.
Nigba
ti Ogbeni Babatunde n so itan ileese eleran igbalode yii fun wa, o ni oun
atiyawo pelu omo awon lawon jo bere ileese yii lodun mewaa seyin ko too
di nla to da loni-in.
Bakan naa lo fi kun oro e pe ohun to je
kawon yato sawon ileese eleran igbalode yooku ni pe awon ki i fi kemika
si eran awon, bee pooku lawon eran tawon n ta.
Ajosepo to dan moran lo
so pe o wa laarin awon atijoba, paapaa ileese NAFDAC.
No comments:
Post a Comment