Ese-o-gbero
l'Ekoo, bee nilu Ikorodu mi titi lojo ti Ijo Asalaatu agbaaye nni, iyen ,
'Allahu Fathiu Al-Mujeeb prayer group international' se akanse adua
l'Ekoo.
Gege bi won se fi to wa leti, Ilu Ikorodu, Nipinle Eko nijo Asalatu yii ti bere ni nnkan bii odun meeedogun seyin ti ibi ijosin won si wa ni ojule kesan-an, opopona olusesi, ni Ibudoko Anibaba, Ikorodu, l'Ekoo.
Lojo
ketadinlogbon, Osu kejila, Odun to koja yii nijo naa labe Oludasile e, Alaaji Sheikh Abdulwaheed
Oluwadamilare Balogun topo eeyan tun mo si "Olulove" gbe akanse adua nla
kan kale nipinle Eko, ti ogoro awon eeyan si ro wa lati awon orile-ede
miran kaakiri ile adulawo.
Ose kan ki adua yii too bere ni Ijo Aladura yii ti bere si ni gba
alejo awon omo egbe yii ti won wa lawon orile ede mi-in. Lara awon orile-
ede ti ogoro awon eeyan ti wa lojo naa ni: Republic of Bene, Togo,
Gabon, Ivory Coast, Ghana, Port Novo ati bee bee lo. Bakan naa lawon
eeyan lolo-kan-o-jo-kan wa lati ipinle otooto lorile ede yii.
Opolopo
ise iyanu lorisirisii l'Olorun se latowo Sheikh Abdulwaheed loju
gbogbo awon eeyan to wa nibi akanse adura ohun, bee ni Sheikh yii fi ase
oro Olorun ninu Kurani tu opolopo ide loju awon eeyan to wa nibe.
Lara awon
ise amin ati ise iyanu ti Olorun se lojo naa ni
Arabinrin kan to wa Lati Ilu Ajase lorile ede Bene Republic ti Alfa yii
so fun un pe nnkan omokunrin oko e ti ku lati aimoye Odun seyin ti
obinrin yii si n jerii si oro naa, sugbon ni kete ti obinrin yii jeri si
ohun ti Agba Alfa yii so ni Sheu yii ti bere si ni i fa aya ninu kurani
to si n pe Olorun ni kikan-kikan leyin iseju die o so fun obinrin yii
wipe ko pe oko e leyin ti won ba pari adua naa bee lo fi n da obinrin
naa loju wipe afefe adua naa ti fe lu oko re ati wipe nnkan omo-okunrin
oko e ti pada sipo.
Ni
kete ti won pari adua ni obinrin yii bere si ni i sukun, o so wipe oko
oun sese pe oun tan to si jerii pe ara oun ti bere si ni i
le pada leyin odun mejo ti nnkan omokunrin oun ti denu kole.
Yato si eyi, opolopo ise iyanu miran lo sele lojo ti akanse adua yii waye ti awon eeyan si bere si ni ri iyanu lesekese.
Opolopo
awon Alfa Nla-nla ni won pejo Lojo adua yii lara won ni: Alhaji Fathiu
Oladokun Ajashe, Benin Republic, olori eka Ijo Al-mujeeb, ni Benni Republic, Alhaji
Abdulazeez Yinusa to je adari agba ijo Al-Mujeeb n'Ilu Cotonou,
Benin Republic, bakan naa Alhaji Abdulganiyu Ajimotokan ti Republican of
Togo ati Alhaji Abdulwaheed Abdulganiyu tawon je Alamojuto agba egbe
naa n'Ilu Kano. .
Lara
awon Eeyan nla-nla to wa nijokoo adua naa lojo naa ni Alhaja Muibat
Bisiriyu to je Iya Adeen egbe lati ilu Ajashe, Benin Republic.
Bakan
naa lese gbogbo awon omo egbe 'Allahu Fathiu Al-Mujeeb' kaakiri orile ede
yii ati lati orile-ede Ivory Coast, Bene Republic, Ajashe, Togo, Gabon,
ati awon orile-ede toku pe sibi gbogan adua naa.
Bo ti le je pe gbogbo ojo Aiku, Sande nijo alasalatu yii maa n pejo se asalatu, sibe won tun maa n ya ojo Alamisi, Tosde soto fun adua ti gbogbo Omo egbe yoo si wo aso funfun balawu, sugbon leyin
Osu merin ni akanse adua maa n waye ti gbogbo Omo egbe yoo si wa Lati
awon orile ede miran.
Gege
bi won se fi to wa leti, Ilu Ikorodu, Nipinle Eko nijo Asalatu yii ti
bere ni nnkan bii odun meeedogun seyin ti ibi ijosin won si wa ni ojule
kesan-an, opopona olusesi, ni Ibudoko Anibaba, Ikorodu, l'Ekoo.
No comments:
Post a Comment