Ti a ba n so nipa olorin Musulumi ni Nigeria loni-in, okan ni Alhaji Ahmad Alawiye Najimudeen, eni tawon eeyan tun mo si Alalubarika.
Ojulowo ni, ninu awon olorin Nigeria ti won ti fise won segi ola, ti won si n se daadaa nidii e pelu.
ALAWIYE ti ba MAGASINNI ALORE soro, ekunrere ohun to so ree…
ENI TO N JE AHMAD ALAWIYE GAN-AN
Oruko mi ni Alhaji Ahmad ALAWIYE Najimudeen, eni tawon eeyan tun mo si Alalubarika. Emi naa tun ni Amiru Shuarahi of Nigeria. Itumo Amiru Shuarai ni, olori awon olorin musulumi ni Nigeria.
Imaam ilu Ofa lo fun mi loye ohun lojo ti awon egbe kan ti won n pe ni Yadulahi n se Maolud Nabbiy won. Won fun mi loye yen, bee ni won we mi ni lawani pelu.
BI MO SE BERE ORIN
Odun ti mo le so pe mo bere si ni tele gbajumo olorin islam nni, Alhaji Waheed Ariyo tabi ti mo n mura lati setan leyin won, odun 1993 ni. Adugbo kan ti won n pe ni Akinbiyi ni Idi-oro lagbegbe Musin, l’Ekoo gan-an ni irinajo yen ti bere.
Odun yen ni mo le so pe mo jade sigbangba laarin awon omo ile kewu wa yooku wi pe mo fe siwaju gege bi akorin fun won. Ayeye wolimo Kur’an la se lodun naa lohun-un.
Saaju igba yen ni mo ti n tele Alhaaji Waheed Ariyo, sugbon odun yen gan-an ni mo jade sita lati korin, bi awon egbon wa laduugbo se tewo gba a niyen; atawon omo kewu egbe mi. Won gbarukuti mi, n lo ba dohun loni-in.
Lodun naa lohun-un, awon obi mi lodi si orin ti mo ya sidii e yii, nitori Afaa lo wu won ki n je.
Lagboole tiwa, gbogbo awon omo pata ti won ba bi nibe, Afaa ni won maa n fe ki won je. A ko ni ise mi-in ju ise Afaa lo. Kani ki i se orin ni mo n ko ni, Afaa ni mi o ba je. koda eni to kawe gboye imo isegun oyinbo, Afaa ni. Bee lawon ti won je amofin, ati osise banki pelu, Afaa ni gbogbo won.
Ko si ohunkohun ti eeyan le je, niwon igba ti o ba ti je omo agboole wa, o ni lati je Afaa, nitori ajebi wa niyen.
ODUN TI MO BERE SI SE REKOODU ORIN
Fun gbogbo awon ti ko ba ye, Ibadan ko ni mo ti bere orin o, ilu Eko ni mo ti bere orin. Rekoodu mi akoko, odun 1995 si 1996 ni mo gbe e jade. Ileese kan ti won n pe ni Decca ni mo ti se e ni Abule Oja lagbegbe Akoka, l’Ekoo.
Bolad music lo koko gbe rekoodu mi jade, leyin naa ni ileese Gbadeyanka gbe rekoodu keji jade, Corporate Pictures lo gbe rekoodu keta ti mo pe ni Sharia jade.
Niberepepe mi, rekoodu kan lodun kan ni, bi mo se maa n se e niyen.
BI MO SE PADE IYAWO MI
Alhaja Rukoya Ahamd, eni tawon eeyan tun mo si Basiri mi, lenuuse ni mo ti pade e, studio gan-an la ti ri ara wa lodun naa lohun-un.
Ise ti oun n se nigba yen ni ki a gberin leyin olorin nla. Ti a ba n so nipa akosemose ninu irufe ise bee, okan ni Basiri mi je, o fe je pe ko seni to mo ise naa to lasiko yen.
Rukaya ni gbogbo awon eeyan mo si nigba yen, nibi ti mo ti koko mo on niyen, oju oga lo fi n wo mi nigba naa. Kin ni kan wa ni o, ko tie se bii eni to maa mu orin nise gidi rara nigba yen, oun kan n gberin leyin awon olorin ni, studio lo si maa n wa lopo igba.
O fe ma si olorin kan bayii ti ki i gberin fun lasiko yen, yala onifuji, onijuju tabi awa ti a n korin Musulumi.
Odun yii gan-an lo pe odun metadinlogbon (27) ti mo ti n korin n bo, bee mo ti sayeye ogun odun nidii orin Islam ri lodun 2011, Alhaji Wasiu Ayinde, Pasuma, Malaika, Lanre Teriba atawon olorin Islam nla nla mi-in ni won korin nibe lojo naa.
Lodun yen ni Alhaji Kayode Sideeq to je aare egbe awa olorin Islam, iyen ISMAN pase wi pe enikeni ninu awon olorin Islam ko gbodo wa sibi ayeye ogun odun mi. Esun ti won fi kan mi ni pe, mi o ki n wa sipade awa olorin Musulumi dede. Esun mi-in ti won tun fi kan mi ni pe, mo n ba awon onifuji se ju awon olorin Islam lo. Bi won ko tile wa, Olorun gbakoso, ayeye ohun si larinrirn daadaa.
REKOODU KEJE TI MO SE LO SO MI DOLOKIKI
Rekoodu to so mi dolokiki ni Alalubarika, rekoodu yen si lo je ikeje ti maa se. Eyi to tumo si pe, nigba ti rekoodu mi di meje laye too mo mi.
Olorun ri e ni akoko, Dupe tie ni ikeji, Sharia lo tele e, E se rere ni ikerin; Ope mi ko ti i to ni eleekarun-un; Alubarika ni eleekefa; Alalubarika ni eleeje. Ni bayii, rekoodu ti mo se ti di mokandinlogbon (29).
AWON ASEYORI MI NIDII ISE ORIN
Ti a ba n so nipa ohun ti mo le tokasi gege bi ohun idunnu nidii ise orin, nnkan po daadaa o ti mo le tokasi. Lodun 2010 ni mo ti koko sile mi akoko niluu Ibadan. Masfala Estate lo wa n’Ibadan.
Nigba ti Olorun yoo tun se pabanbari oore fun mi, o tun wa kole nla fun mi ni Owode nipinle Ogun. Bee ni ise n lo lowo lori omi-in ti Olorun ti se.
Agba iyanu lawon oore ti Olorun n se fun mi nidii ise orin. Se mo so pe lenu ise orin naa ni mo ti pade iyawo mi, eni ti ko fi ojo kan ba mi ninu je ri. Lojoojumo ni mo n dupe, nitori ki i se gbogbo eeyan lo niru oore ofe bee, paapaa laarin awa olorin Islam.
Ninu ise orin yii naa, mo dupe wi pe mo ba egbe pe, ninu e naa tun ni irawo ti Olorun fun mi latigba ti mo ti bere. A dupe wi pe bi awon kan tie lawon fe le wa nidii ise naa, sibe Olorun ko je.
Oore manigbagbe ti Olorun se fun mi nidii ise yii ni pe, o mu mi duro, o tun fese mi rinle ninu e. A dupe wi pe a ri aanu Olorun gba nidii ise yii.
ISORO TO N KOJU AWA OLORIN MUSULUMI BAYII
Awon idojuko wa nidii ise orin, ki i se oro emi nikan o, gbogbo awa olorin pata la jo n foju winna e. Abi nigba ti eeyan ba se awo orin, to ti lero wi pe, rekoodu yen a fe ta to egberun lona ogorun-un (100,000) to wa je pe egberun lona meedogun (15,000) si egberun lona ogun (20,000) pere leeyan a ri ta. Ibanuje gidi ni o, pelu gbogbo wahala ti eeyan maa se ati owo pelu.
Sugbon ta a ba wo o daadaa, a o ri i wi pe awa naa la fowo ara wa fa opolopo wahala yen. Bee tun ni olaju to tun gbaye kan bayii, pelu bi won se n gbe orin sori foonu, eyi gan-an lo tubo ba opo olorin laye je.
A ti kuro ni aye CD bayii, nise lawon eeyan n gba orin sori kaadi, iyen memory card.
Ojo iwaju orin Islam n ba mi leru gidigidi, nitori awa ta a wa nibe lasiko yii, okanjuwa lo poju ninu wa.
Egbe to maa n polongo orin wa, iyen MAAN, ti pe wa ri. Ohun ti won si so lojo naa ni pe, ki a jokoo soro lori rekoodu alasepo ti a n se yen lori bi a se maa fi odinwo si i. Alhaji Abdul-waheed Mosebolatan lo wa nipo lodun yen. Emi gege bi enikan, mo da duro lodun naa, ohun ti mo si so fun egbe wa nigba yen ni pe ki a ma se e mo. Mo je ki won mo pe, nigba ti a ko ti i maa se e, awon maketa ti won n ra orin wa, won le fun wa ni milionu kan naira, lori ise kan. Emi ti e n wo yii, lori rekoodu kan, mo ti gba milionu meta naira ri, bee ni mo ti gba idaji milionu kan naira daadaa. Nigba ti mi o tie ti i loruko rara, mo ti gba egberun lona irinwo naira (N400,000) ri, owo ti mo si n so yii, lori AUDIO CD nikan ni o, ko ni fidio ninu, nitori oto ni maa gbowo yen, awon naa ni won tun maa ra aso fun mi, ti won tun maa sanwo feni to ba ya fidio yen, sugbon gbogbo e pata lo ti baje loni-in, ko siru anfaani bee yen mo. Ni bayii, awa la n se gbogbo e funra wa, ti a ba tun gbe e dodo maketa, iyen le tun ni ki a lo mu owo wa, ti oun yoo fi se posita. Leyin e ni won a tun ni ka lo ya fidio wa funra wa, gbogbo e ti daru pata.
Gbogbo radarada ti won n se yen, won fi ba oja orin islam je ni o, itan ti onitiata mi ko ko ri, lowo awon olorin Islam le ti maa ri i. Won ti ba a je patapata, bee ni ko si aponle kan bayii fun orin Islam mo. Rekoodu to je ojulowo ti eeyan kan ba da se ki i ta mo, afi elero repete, ti nnkan ti won ko jo gan-an ko ba Islam mu.
Nibi te e ti maa mo pe awa olorin Islam ni a n koba ara wa, nise ni okan ninu wa so pe ki awa ti a je irawo nla da egbe kan sile, a da a sile, bee la sepade bii eemeta, nibi ipade yen naa la ti fenuko wi pe a ko ni i se rekoodu alajospeo fun odun kan si meji, ki a wo ohun to maa sele si rekoodu aladase; ti a maa n dase nigba kan. A wo o wi pe boya ti a ba se bee, o le da ogo rekoodu adanikan-se pada. Nibi ta a foro si niyen, sugbon nise ni awon kan ninu wa ko lati tele e, loju tiwon, rekoodu alasepo ni won ro pe o n se awon lanfaani, sugbon awa mo pe iro ni, igbesi aye iro ni won n lo, ohun ti won ko to ni won n pera won.
Ohun ti won n so ni pe, ohun to ba ti ro kaluku lorun ni ko se. won ni eni ti ko ba wo fun ni ko ma se e, awon si n gbadun e ni tawon.
Ohun to kan dun mi ju ni pe, awon ti awa ba niwaju, won ko se e bayii rara, awon bii Alhaji Abdullahi Akinbode, Lateef Oloto, Waheed Ariyo, Kabira Borokinni, awon ti won korin Islam niyen ti aye ra rekoodu won daadaa. Awon gan-an ni won je ka ri ere je nidii ise yii. Awon ko se ohun ti awon eeyan wa n se loni-in, iyen lawa naa ba, ti a si korin gidi jade, ti aye si tewo gba a.
Nigba ti aye di rekoodu alasepo yii lo di pe irawo tuntun kankan ko jade mo ninu awon olorin Islam. Abi eni to fe se rekoodu, to lo ko irawo olorin jo, tiru orin bee ba jade, irawo yen lawon eeyan a maa wo, abi ta lo fe wo eni ti won ko ti i mo.
Nibi ti rekoodu alajosepo ti dara ni ti awon irawo nla meji tabi ju bee lo ba jo korin papo, bii Ahmad Alawiye ati Ayeloyun, awon ololufee Ayeloyun maa tori e ra a, bee lawon ti won ko le maa gbo Alawiye naa yoo ra a nitori tie. Bee lo maa nitumo gidi.
MO NI OGA NIDII ISE ORIN
Nidii orin Islam, eni ti mo le pe ni asaaju mi naa ni Dokita Abdul-Waheed Ariyo. Ki Olorun ba mi ke won. Ohun to se pataki fun gbogbo omoose ni ki won se daadaa pelu oga won, iru omoose to ba se bee, o di dandan ko jere nigbeyin oro. Omo gidi ni mi leyin oga mi Ariyo, mo duro ti won loju aye won ati leyin won. Mo dupe wi pe gbogbo nnkan ti mo se fun won pata ni mo jere e.
Nigba ti won pe eni aadota odun laye, a se ayeye repete, gbogbo aye ni mo pe wi pe ki won wa ba wa sajoyo nla. Gbogbo awon eeyan nla nla ti mo mo ni mo pe, gbogbo won ni won wa, won si se daadaa pelu.
Bee nigba ti won jade laye, mo da inawo temi se ni, bee lo ye won. Ayeye fidau ti mo se fun won ni Combo Hall ninu ogba LTV8 l’Ekoo, mi o reeyan to seru e fun won. Baba yen ni asaaju mi ta a ba n soro nipa orin Islam. Elomi-in ti mo tun ni, oun ki i se olorin islam ni tie, emi ko ni i maa ba eeyan se, ki n maa wa se seyi-sohun rara, lagboole orin, mo tun ni oga kan, egbon mi daadaa ni, bee lo tun je awokose mi, awon naa Alhaji Wasiu Alabi Pasuma.
Nipa egbe PISMAN, ododo la fi gbe e kale, notori e ni ko se yinge rara. Ase Olorun la fi da a sile, bee la fi ipile e lele lori ododo. Nitori Olorun, nitori Anobi la fi da egbe PISMAN sile, ati pe okanjua tawon kan n se la tako, bee enikan ko le maa so pe oun ni oun yoo maa solori wa lo titi laelae. Gbogbo wa la jo n korin, bee oye egbe, gbogbo wa naa la jo ni eto si i.
Bo se duro loni-in, a ko fi okanjuwa si i ni. Ki i se dandan ni ki n je aare ninu egbe yen, bee ko pon dandan fun mi ki n je olori nibe, emi ko wa a moya rara, nigba ti mo ti se e fun bii odun kan aabo, ti egbe ti fese rinle daadaa, funra mi ni mo gbe e sile, koda eni to je aare wa ko mo wi pe oun loye ohun maa kan. O je e, a si dupo lowo Olorun wi pe, ilosiwaju rere n ba awon omo egbe wa.
Ile nla ti mo ko si Atan Ota, emi ko o, Olorun ni. Bi Olorun ko ba ko o, gbogbo eni to ba n se e kan n se e lasan ni o. Olorun lo falubarika si ise mi o, oun lo ran mi lowo, to ran mi se. Olorun lo fise yin mi o, mo dupe fun Olorun pupo, leyin eyi to se ni Atan Ota, Olorun tun ti se omi-in o, mi o kan pariwo e rara ni. Mo dupe lowo Olorun fun ise iyanu e ninu aye mi.
No comments:
Post a Comment