
Okan lara awon omo oloogbe ohun, Ogbeni Emmanuel Adejumo, eni ti awon eeyan tun mo si Boisala lo soro ohun loruko molebi. O ni, ojo meji ni eto isinku ohun yoo fi waye laarin ojo kefa si keje ninu osu kejila odun yii.
Te o ba gbagbe; lojo keje osu kewaa odun yii ni Baba Sala jade laye leni odun mejilelogorin (82) nile e niluu Ilesa, ipinle Osun.
Gbajumo nla lokunrin alawada yii; kaakiri agbaye ni won si ti mo on, eyi to mu ijoba orile-ede yii paapaa fun un lami eye MON, iyen Member of the Order of the Niger (MON).
Bi eto ohun ba se n te siwaju si i, a o maa fi to yin leti.
No comments:
Post a Comment