IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Monday, 15 October 2018

EWO WON O, AWON OMO YORUBA TI WON N FI ORIN GBE ORUKO ORILE-EDE YII GA LOKE-OKUN



Latowo Taofik Afolabi
Gbogbo awon olorin ti a mu wa fun yin yii ni won n lo ogbon ati imo ti Olorun fun won gbe oruko orile-ede yii ga loke-okun. Imo orin ti Olorun fun won lo so won dolokiki laarin awon dudu ati funfun niluu oyinbo. Eyin naa, e waa nnkan fidile lati gbadun ara yin pelu awon omo Oodua ti won n se gudugudu meje ati yaaya mefa nidii ise orin ti won ya laayo.
Yinka Rythmz
 Ko si bi won yoo se daruko awon omo orile-ede yii ti won n se daadaa loke-okun,  won ko ni i rin jina ti won yoo fi daruko osere nla yii ti won fi joye Oluomo ati Atolase ilu Texaz yii si i. Bakan naa losere yii tun je dokita alabere niluu oyinbo. Oun kan naa ni won n pe ni Omo Somebody, opo ami-eye ni Yinka Rythmz ti gba. Orile-ede Amerika lo n gbe ni tie

Seriki Adewale Akanji Barryshowkey:  
Ko digba teeyan ba n juwe e ki won too mo Adewale Akanji ti gbogbo aye mo si Barryshowkey, eekan nla kan losere yii ninu awon olorin ti won n se daadaa loke-okun. Ile ta si i ti osere omo bibi ilu Ibadan yii ti wa loke-okun. Barryshowkey ti gbe opo rekoodu jade, o si ti gba ami-eye lorisirisii.




Eniola Abiodun Elias(Ayangbajumo)
 




Ogbontarigi lobinrin yii ninu awon olorin ti won se daadaa loke-okun. Bi Ayangbajumo se forin gbe ogo orile-ede yii ga, bee lo n fi lulu dara lorile-ede Amerika. Ayangbajumo ki i se olorin tabi onilu kekere. Laipe lo si ileese nla kan sorile-ede Amerika to n gbe.
Opo rekoodu ni Ayangbajumo ti gbe jade, bee loun naa ti gba ami-eye repete.



Segun Akinjagunla: Osere yii ki i se eeyan yepere ninu awon olorin ti won n se daadaa loke-okun, Oluomo  ni won fi oun naa je. Opo rekoodu ni Segun Akinjagunla ti gbe jade. Lara awon rekoodu to ti gbe jade ni Oluomo, Asiko mi,laipe yii lo gbe orin 'Originality jade. Akinjagunla naa ki i se olorin kekere rara.Ilu London ni Akinjagunla n gbe, to ti n jaye oloba











Anjola Loe Bravo.

Lojokojo ti won ba n daruko awon omo orile-ede yii,ti won se n daadaa nidii ise orin,o daju saka pe won yoo daruko osere yii si. Ilu Ireland ni Bravo wa ni tie. Osere yii ni won fi joye oba gbogbo awon olorin juju ni Ireland. Opo rekoodu ni Anjola ti gbe jade, bee lo ti gba ami-eye ti ko lonka nidii ise orin.

Arabian Jerry: 
Orile-ede Amerika ni Arabian Jerry ti won n pe ni Mr Brabra of the world wa to ti n gbe ogo orile-ede yii ka. Eeyan nla ni Arabian ninu awon olorin ti won je omo orile-ede yii ti won n gbe loke-okun. Osere nla yii naa ti gbe opo rekoodu jade, bee loun naa ti gba opo ami-eye.


Queen Seidat Almubaraq


Onimo to peye, to mo tifun-tedo orin naa Queen Seidat Almubaraq. Orile-ede Amerika larewa obinrin yii wa to ti n forin da awon eeyan laraya. Osere yii ki i se majesin ninu awon to n korin Islam. 

Ami-eye ti ko lo n ka lo ti gba nidii ise orin, oun naa ti gba opo ami-eye.  




Alaaja Rodiyat Ayinke Adeboye: 
Okan ninu awon olorin ti won n se daadaa loke-okun ni Alaaja Rodiyat Ayinke Adeboye tawon eeyan mo si Hello Olohun. O daju pe nibikibi ati lojokojo ti won n ba daruko awon akorin gidi, paapaa orin esin, won ko ni i rin jina ti won yoo fi daruko osere  nla to je iyawo manija Pasuma, Mattew Ajiboye ti wo n pe ni ididowo si i.

Rekoodu meta lobinrin naa ti gbe jade, ti eleekerin n bo lona bayii, bee lo ti gba opo ami-eye nile yii ati loke-okun.Ilu Dublin



 Olusegun Ayomikun:
Okan pataki ninu awon omo orile-ede yii, ti won fi ogbon ati imo ti Olorun fun won gbe oruko orile-ede yii ga loke-okun ni Oluwasegun Ayomikun tawon ololufe e mo si Beta Man.

Laarin awon eeyan dudu atawon oyinbo alafo funfun ni won ti mo okunrin yii gbe ojulowo omo Yoruba to n lo imo t'Olorun fun un nipase orin to n ko so Naijiria di orile-ede pataki laarin awon oyinbo lokunrin yii.

Beeyan ba ri Beta Man nibi to ti n korin, eni bee yoo kan saara si ise opolo, gbogbo irinse orin pata losere nla yii mo on lo. Lara awon rekoodu to ti gbe jade ni 'Dide si iranlowo mi,Omo tuntun, bee lo ti gba  polopo ami-eye nidii ise to yan laayo. Ilu London loun naa wa to ti n gbe orin re ga. Oluwasegun ree, ojulowo omo Yoruba to n gbe oruko wa ga loke-okun ni.    




Taofeek Igisekele: 
Orin fuji losere yii n ko ni tie, o to ojo meta to ti wa loke-okun, bee lo ti gbe opo awo orin gidi jade. Boya ni ode ariya kan sele ni Amerika ti won ko ni i pe Igiselekele si i. Ohun to tun je kawon eeyan feran osere yii daadaa
ni pe arewa okunrin ni.

Mayor Akeem Alamu

Gbajugbaja lokunrin yii ninu awon omo orile-ede yii ti won n se daada loke-okun. Ko si bi won yoo se daruko awon olorin ti won je omo orile-ede yii ti won n se daadaa niluu oyinbo ti won ko ni i daruko okunrin yii si i.
Orile-ede Amerika ni Alamu wa to ti n se bebe. Inu osu kejila odun yii losere naa fee sayeye irinse tuntun to sese ra. 

Safejo Ajani Amama
Ogbontarigi lokunrin yii ninu awon olorin ti won n se daadaa loke-okun, orin fuji ni Amama ti won tun n pe ni Oga Nla 2 fi gboruko orile-ede yii ga lodo awon oyinbo.
Opo rekoodu ni Amama ti gbe jade, bee lo ti gba opo ami-eye nidii ise orin to yan laayo.


No comments:

Post a Comment

Adbox