Ni tile to mo loni-in, lojokojo ati nibikibi ti won ba n soro nipa osere fuji toruko re gbile kari aye, paapaa lorile-ede Amerika to n gbe, won ko ni i rin jina rara ki won too daruko Barryshowkey si i, okunrin naa ti di araba nla tapa omode ko ka laarin awon olorin gbogbo, o jare.
Ko si ode ayeye tabi pati kan ti won ti n wa olorin fuji to peregede, to to gbangba sun loye, ti won ko ni i pe Barryshowkey lati waa korin fun won nibe l'Amerika, oun laayo gbogbo awon omo alafe nibe.
Bakan naa Ojutole gbo pe okunrin ti won fi joye Seriki gbogbo olorin patapata n palemo ayeye nla kan to fee se fun ayeye ojoobi baba e, iyen Dokita Sikiru Ayinde Barrister. Lati awon orile-ede bii Canada, London, Italy ati ni gbogbo Yuroobu pata lawon eeyan yoo ti wa lati seye nla yii, eyi ti yoo milu titi.
No comments:
Post a Comment