IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Friday, 28 September 2018

TI ESIN IBO OSUN KO BA TE ADELEKE LORUN, E JE KO GBA ILE-EJO LO- AARE MUHAMMED BUHARI

Aare orile-ede yii, Muhammed Buhari ti so pe ti esin abajade ibo gomina ipinle Osun ko sese koja yii ko ba te awon omo egbe PDP lorun, ki won tete gba ile-ejo lo lati tako abajade esin idibo naa.

Aaree soro yi latenu akowe e nipa eto iroyin, Ogbeni Sanni Garba, o ni ko si ohun to buru bi Adeleke atawon omo egbe oselu PDP ba gba ile-ejo lo bi abajade ibo naa ko ba te won lorun.

Bakan naa lo ki gomina tuntun ti won sese yan ohun, Alaaji Gboyega Oyetola ku oriire. O ni abajade esin naa fihan pe awon ara Osun nifee egbe oselu APC. 

No comments:

Post a Comment

Adbox