IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Wednesday, 12 September 2018

ORIIRE NLA NI AARE MUHAMMED BUHARI JE FUN WA LORILE-EDE YII-YEFADOT

Asaaju awon obinrin nile Yoruba fun ajo to n ri si bi Aare Muhammed Buhari yoo wole leekan si i iyen 'National Committee of Buhari Support groups', Oloye Yetunde Babajide, to tun je alase ati oludasile ileese Yefadot Group of companies ti so o di mimo pe oriire nla nijoba Aare Muhammed Buhari je fun gbogbo awon omo orile-ede yii.

Lasiko to n ba wa soro lofiisi  e to wa ni Ojodu Berger, nipinle Eko, Oloye Babajide, to tun je Iyalode ilu Ojodu, so pe gbogbo eni to fokan si boro orile-ede yii se n lo yoo mo pe adura nikan lo ye ka fi maa ran Aare Buhari lowo, nitori pe nnkan tawon kan ti baje lo n tun se lojoojumo. 'Ti e ba wo o, e o ri pe iwa ajebanu ati ka se owo ilu basubasu ti din ku daadaa, ko seni to n se yanfuyanfun mo, eyi ti ko ri bee laye ijoba egbe oselu PDP.

Bakan naa lori  nibi ise awon akanse, gbogbo ohun ti ko sise  daadaa mo, to ti dokuu nijoba Buhari ti n ji pada. oro ise agbe, tawon eeyan n sa fun, ti di ohun tawon eeyan n lo sidii e bayii nitori iranlowo ti won ri gba lowo ijoba. Eto aabo n ko,ise takuntakun nijoba n se'.

Ohun to ye kawon eeyan orile-ede yii se ni pe ki won pawopo kijoba yii te siwaju, ki gbogbo wa le jegbadun ijoba to n fe daadaa
fun wa.      

No comments:

Post a Comment

Adbox