IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Wednesday, 12 September 2018

AYANGBUREN TILUU IKORODU, OBA KABIRU SHOTOBI, NI YOO SISO LOJU AYEYE 'YORUBA MOVIES AND MUSIC FESTIVAL' TODUN YII

Ayangburen tiluu Ikorodu, Alayeluwa Oba Abdulkabir Shotobi, ni yoo siso loju odun igbelaruge  ere ati orin Yoruba eyi ti won n pe ni 'Yoruba Movies and Music Festival' todun yii.

Gege bi a se gbo, lasiko ti oludasile ayeye yii, Otunba Omotayo Ogunlade, saaju awon osere nla bii; Iya Awero, Remmy Shita-Bey, Awofe Afolayan, Adewale Elesoo, Bimbo Akisanya, Nike Peller, Yetunde Wunmi, Alaaji Ade Aderenle, Doyin Aggrey, Seri Ilerika, Keji Yusuff, Wale Hassah ati AlaajiTajudeen Gbadamosi lo saafin Ayangburen ni won je ki oba alaye yii mo pe awon ni yoo siso loju ayeye yii lojo kokanla, osu kewaa, iyen lojo keji tayeye naa bere.

Ohun to tun waa je kojo yii so eso rere fun oludasile ayeye yii atawon ti won jo lo ni nipe,won tun ba Oba ilu Igbogbo laafin Ayangburen, toun naa si bawon jokoo lati sepade pelu Ayagburen, bee loba Igbogbo fi won lokan bale pe oun yoo  kowo rin wa sibi ayeye naa pelu Oba Ikorodu ni.

Ninu oro e, Otunba Ogunlade so pe nitori ki awon ere ati orin Yoruba ma ba a lo soko iparun lo je kawon sagbekale odun naa lati je kawon odo asiko mo ipa ti ere ati orin n ko ninu igbelaruge asa ati ise Yoruba.
Lasiko to n fesin soro awon alejo e yii, Oba Ikorodu so pe o di dandan koun wa nibi ayeye naa, nitori pe oun mo riri ipa tawon onifiimu n ko lawujo Yoruba.

Lati ojo kewaa si ojo kejila layeye yii yoo waye ninu gbongan Blueroof to wa ninu ogba ileese telifisan LTV 8 to wa niluu Ikeja. 

























No comments:

Post a Comment

Adbox