Olootu iwe iroyin naa, Pasito Oyekunle Babarinde to tun je onkotan iwe itan 'Yoruba ni tooto' lo gba iko ayeye yii lalejo lojo naa.
Ninu oro e, Omotayo, gbosuba nla fun Alariya Oodua fun ipa nla ti won ko lati je ki ede ati asa Yoruba tun lo soke si i, ko si ma di ohun igbagbe lasiko ti wa.
Bakan naa lo sadura iwe iroyin yii pe iwaju lopa ebiti won yoo ma a re si. Bee lo ro Alariya Oodua lati ran ayeye yii lowo, ko le e di ohun ti gbogbo aye yoo gbo nipa e.
Lasiko to ki iko yii kaaabo sofiisi e, Pasito Babarinde naa lu iko naa logo enu fun bi won se n se igbelaruge fun orin ati fiimu Yoruba. Oun naa fi won lokan bale pe Alariya Oodua yoo fowo-sowo-po pelu won ki erongba ati gbe ede ati asa Yoruba soke le e di mimuse.
Ojo kewaa si ojo kejila osu kewaa layeye yii yoo waye ni gbongan Blueroof to wa ninu ogba ileese telifisan LTV. Ayangburen ilu Ikorodu, Oba Abdulkabir Shotobi ni yoo siso loju ayeye yii.
No comments:
Post a Comment