IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Tuesday, 11 September 2018

OJO NLA LOJO TI MAGASINNI CITY PRIDE FUN OLOYE YETUNDE BABAJIDE LAMI-EYE NLA

Nitori ilosiwaju ati idagbasoke to mu ba orile-ede yii, laipe yii ni magasinni 'City Pride' fun oga ileese Yefadot Group of companies, Oloye Yetunde Babajide lami-eye nla.

Ami-eye yii tawon eeyan pataki lawujo wa nibe ni won fun obinrin oloselu nla yii to tun je Iyalode ilu Ojodu, nipinle Eko lati fi se koriya fun un fawon ise idagbasoke tileese n se, paapaa lati ri i pe ojo iwaju awon eeyan orile-ede yii dara. 

Gbajugbaja ajafetoo awon eniyan lorile-ede yii, Dokita Joe Odumakin lo gbe awoodu naa le Oloye Babajide lowo.

Ninu oro e, Oloye Babajide, so pe ko si ohun to je oun logun ju bi awon eeyan orile-ede yii, paapaa awon odo yoo se ni ojo iwaju gidi, O ni  opo awon odo ni won ti janfaani nla lati ileese oun, eyi to di ise ati osi kun lorile-ede yii.

Bakan naa lo gbosuba nla fawon to sagbateru ami-eye naa, o ni ohun ti won se yii yoo tunbo je koun te siwaju ninu ise rere toun gbe dani lati opo odun seyin.






No comments:

Post a Comment

Adbox