Ambode ati Sanwolu |
Gege bi Ojutole se gbo, oro kan ti won so pe Ambode so nibi ayeye Ojude Oba to waye niluu Epe lojo keji odun Ileya wa lara ohun to n bi Asiwaju ninu, to si fibinu so pe oun yoo ri i pe Ambode ko wole gege bii oludije ipo gomina ninu egbe awon.
Eni to tu asiri yii fun wa so fun wa pe lasiko ti won soro nipa eni ti yoo dupo loruko egbe oselu APC nipinle Eko ni Ambode so pe kawon eeyan ma wule da ara won laaamu rara, o ni toun ba ti gbe owo nla fun Asiwaju, toun si tun gbe owo roburobu fawon agba egbe oselu APC, oun ni won yoo fa kale loruko egbe naa ninu ibo abele.
Oro yii la gbo pe awon eeyan kan ka sile, ti won gbe lo fun Tinubu nile, bi asaaju egbe oselu yii se gbo o, lo fa ibinu yo, lojuese lo si ti wa eni ti yo dije pelu Ambode ninu ibo abele egbe APC yii.
Eni ti won so pe Asiwaju atawon asaaju egbe APC bii Kadina James Odunmnbaku ti won pe ni Baba Eto fe ko dije pelu Ambode, lokunrin ti won n pe ni Jide Sanyaolu Sanwonolu, okunrin naa si ti gba foomu lati dije ipo gomina loruko egbe APC nipinle Eko bayii.
Hamzat, lasiko to n da foomu e pada |
Elomi-in to tun fa wahala nla fun Ambode bayii ni Obafemi Hamzat, a gbo pe okunrin yii naa ti gba foomu lati dije ninu egbe APC. Eyi tumo si pe awon meta ni won ti jade lati dije loruko egbe oselu APC bayii. Bakan naa la gbo pe Asiwaju ti so pe eni to ba fee lati dije,ko jade, eni tawon omo egbe ba si dibo fun lawon yoo gbe kale loruko egbe awon.
Nibi to toro de bayii, ohun to foju han ni pe, nnkan ko rogbo ninu egbe oselu APC l'Ekoo. Ara o rokun, bee lara ko ro adie, okan Ambode paapaa ko bale mo
No comments:
Post a Comment