Gbongan igbalode toruko re n je 'Time Square' to wa ni ikeja layeye naa ti waye. Lati bii aago kan osan lawon eeyan ti n ya wo gbongan nla yii, nigba ti yoo fi di aago merin irole ibe ko gbero mo. Okunrin adari ayeye ti won n pe ni MFR lo koko dari ayeye yii lara oto, ko too di pe Ronke Osodi Oke naa dari e pelu e.
Saaju ki Alaaji Wasiu Alabi Pasuma to je olorin ojo naa too korin lawon osere nla bii gbajumo olorin emi ati juju, Dotun Future ati ilu mo on ka sorosoro ori telefisan, Bimbo Badmus ti gbogbo aye mo si Madiva naa ti koko forin da awon eeyan laraya.
Leyin won lawon osere bii: Golden Stone, Omo ileri, Doctor J, Fair man, Parol Nelson, Terryscophy, Mc rock boy, Tynoni, Doctor j, Demolat, Oluomo Hamowiy naa korin.
Ni nnkan bii aago meje ale ni Pasuma bere orin re, ti gbogbo inu gbongan n dun yugbayugba, bee ni Ola Funke atawon ore e pelu awon alejo e fese rajo Oga Nla awon onifuji.
(Oloto tiluu Oto awori kingdom) Oba Asiwaju tiluu Kweme
Alaaji Shuaib Fatai Ajidagba “AJIFAT” alaga ijoba ibile idagbasoke Ajeromi Ifelodun,Oloye Afolabi Ojo. Bee lawon osere bii Madam Saje, Seyi Fuye, Baba Dugbe, Afefe Oro, Iya Oriki atawon mi-in.
Ju gbogbo e lo, gbogbo awon eeyan ti won lanfaani wo fiimu Anispark ni won so pe ise opolo ni Ola Funke se sinu e.
No comments:
Post a Comment