IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Thursday, 20 September 2018

ADAJO TI FI AWON TO LU ONAREBU TIMOTHY OWOEYE, ASOFIN IPINLE OSUN TI WON MU NIBI TO TI N WE NI JIBITI SOGBA EWON


Latowo Taofik Afolabi

Ile-ejo giga kan, to fikale siluu Osogbo, nipinle  Osun,  ti  ti fi awon mejo kan ti won lu adari omo egbe to poju nile igbimo asofin ipinle Osun, Onarebu Timothy Owoeye ni jibiti owo tiye re je milionu mejidinlogorin pamo sogba ewon.  

AWON AFUNRASI NAA NIGBA TI WON KO WON DE ILE-EJO
Awon eeyan naa ni: Kazeem Agbabiaka, eni ogoji odun, Abdulrasheed Ojonla, eni odun marundinlaadota, Femi Oyebode, eni ogbon odun, Babatunde Oluajo, eni aadota odun, Adebiyi Kehinde, eni odun mejilelogoji, Oyebamiji Oyeniyi, eni odun mejilelogbon, Ismaila Azeez, eni odun marundinlaaadota, ati Awodunmola Kehinde, eni odun merinlelogoji.
WON N DA WON PADA SOGBA EWON
Lasiko to n gbe igbejo e kale, adajo kootu yii,Ogbeni  Olusegun Ayilara, pase  pe kawon olopaa  loo fawon odaran afunrasi yii pamo sogba ewon titi dojo kejidinlogbon, osu kesan-an,  tigbejo yoo tun bere ni pereu.   
ONAREBU TIMOTHY OWOEYE
Ninu oro olopaa ijoba, ASP John Idoko lo ti salaye funle-ejo pe inu osu kerin ati osu keje lawon eeyan yii huwa ibaje yii ladugbo kan ti won n pe ni Oluajo, niluu Osogbo. 

Olopaa yii te siwaju ninu oro e re pe, awon eeyan naa fogbon gba owo nla yii lowo Onarebu Owoeye lori pe awon yoo ba a setutu nitori iran  iku ojiji ti won ri si i. Sugbon nibi to ti n fe yii lawon ti won lawon fee ran lowo yii tun ti de awon eeyan kan si i lati waa mu un lasiko to n we yii.

No comments:

Post a Comment

Adbox