Ohun tawon eeyan ko lero rara lo sele nibi eto idibo gomina to waye nipinle Osun lojo Abameta, Satide to koja yii. Nibi toro si gbe duro bayii,kinni ohun ti di wahala si ajo to seto idibo naa, iyen INEC. Ikede ti ajo yii se bayii ni pe ojo Tosde to n bo yii latundi ibo yoo waye
Kaakiri orile-ede yii atawon to wa loke okun lo jo pe won n feti leko lati mo koko abajade esi ibo to waye nipinle Osun lana’an Satide, ojo Abameta.
Sugbon bi awon eeyan se n reti, ti won n r’emu to, o jo pe ileese to n ri si eto idibo ko ti i mo odo ti yoo da orunla si.
Se ni kete ti ibo ti pari lana’an lawon esi ibo lolo-kan-jo-kan ti gba igboro kan, lojuese naa si ni ileese INEC ti so pe enikeni ko gbodo tele esi ibo ohun, nitori ileese yen nikan lo lase lati gbe e jade. Bee ni ajo INEC tun fi kun un pe, awon to n gbe esi ibo jade lorisirisi ti ki i se latodo awon, iwa odaran ponbele ni won n hu.
Bi awon iwe iroyin kan se gbe e laaro oni wi pe, Seneto Nurudeen Ademola Adeleke lo n le iwaju, bee lawon mi-in naa tun so pe Gboyege Isiaka, omo egbe oselu APC ni.
Bi oro ohun se wa ree, ti kaluku feti leko lati mo ohun ti yoo je abajade ohun. Ni bayii, iroyin to tun gba igboro kan bayii ni pe o see se ki atundi ibo waye lawon ibi kan ti won ti fagile esi ibo latara awon kudie-kudie kookan to waye nibe.
Awuyewuye loro ohun koko jo, sugbon nigba to di osan Sannde, ti ireti awon eeyan ti fere pin, lasiko igba yen ni okan lara oga agba ajo INEC, Ogbeni Josph Afuwape kede wi pe awon ko ni i le so pe egbe oselu kan bayii pato lo jawe olubori laarin PDP ati APC.
Ninu e naa lo ti salaye pe ibo egberun lona igba-o-le-erinle-laaodota ati ibo mokandin-leedegbinrin (254,699) ni Ademola Adeleke omo egbe oselu PDP ni, nigba ti Isiaka Oyetola toun dije labe asia egbe oselu APC ni tie ni ibo egberun lona igba-o-le-erin-le-laaodota ati ibo oodunrun-o-le-marun-un-din-laadota (254,345).
Nigba ti Iyiola Omisore, to dije loruko egbe oselu SDP, to siketa ninu idije ohun ni ibo egberun lona eji-din-ni-aadoje-o-le-mokandinlaadota (128,049).
Esi ibo to je iyato laarin ohun ti egbe oselu PDP ati APC ni je ibo ota-le-loodunrun-o-din-meje (353), nigba ti ibo ti won fagile lawon ibi kan je egberun meta ati ibo eedegbeta- o-le-mokandinlaadota (3,549)
Ajo INEC ti so pe yoo soro fawon lati kede eni to wole ibo gomina ohun, ati pe laipe yii ni atundi ibo yoo waye lawon ibi ti won ti fagile tele.
Awon ibi ti won ti fagile ibo niwonyi; Orolu, ibi idibo meji ni won fagile nibe, bakan naa ni won fagile awon ibi idibo lawon bii Ife South, Ife North ati nibi kan niluu Osogbo.
Ohun ta a gbo ni pe ojo ketadinlogbon osu yii ni atundi ibo yoo waye lawon ibi ti won ti fagile won.
Saaju asiko yii lawon omo egbe oselu PDP ti n jo kiri ipinle Osun, sugbon pelu ohun to sele yii, nibi ti oro ohun yoo yori si, iyen di igba ti ajo eleto idibo ba kede ojo ti atundi ibo yoo waye.
No comments:
Post a Comment