Yoo pe e daada kawon omo egbe awon ololufe Kabieesi Owuro La wa, iyen 'Kabiiesi Owuro la wa Fans Club' too gbagbe ojo Eti, Frade to koja yii. Ojo naa ni won sefilole egbe naa niletura 'Vertical Hotel and suite' to wa niluu Igbogbo, nikoja Ikorodu, nipinle Eko.
Bi i omi lawon eeyan ri ninu gbongan ti won lo, ti isale naa tun kun fawon ololufe gbajumo sorosoro yii. Awon gbajugbaja sorosoro meta, Oloye Abiodun Adeoye tawon eeyan mo si Afefe Oro, Kaseem Ajibola ti gbogbo aye mo si Baba Labule ati Lekan Balogun ni won dari ayeye yii.
Bawon olola se wa nibe, bee lawon baale, awon oloye, ayeye yii ko si yo awon otokulu atawon afenifere sile.
Lara awon osere ti won forin aladun da awon eeyan laraya lojo yii ni: Alaaji Sule Alao Malaika, Efanjeliisi Paul Omo Abule ati Iya Cairo. Bee lawon olorin takasufee lolokan-o-jo kan naa n dara lojo yii.
Yato si ifilole yii,wo tun fun awon eeyan pataki kan lami-eye lojo naa. Die lara awon foto ti Ojutole ya nibi ayeye naa ree.
No comments:
Post a Comment