IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Friday, 7 September 2018

GONGO SO LOJO TI OTUNBA JESU KO REKOODU 'ARABARIBITI' JADE

Ojo nla ti gbajumo olorin emi nni, Otunbajesu Oludele ko le gbagbe boro lojo Aiku, Sannde, to koja yii. Ojo ohun lokunrin naa tawon ololufe e tun n pe ni Mr. Spirit ko rekoodu e tuntun to pe ni 'Arabaribiti' jade.Bamubamu lawon eeyan kun gbongan 'Deborah Lawason Event Centre' to wa ni Omole tayeye naa ti waye. 

Adura ni won koko fi bere eto yii ni nnkan bii aago meta osan, nigba ti yoo fi di aago merin irole, inu gbongan yii ko gba ero mo. 

Bawon ololufe Otunba Jesu se wa nibe, bee lawon osere kun ibe daadaa,tawon afenifere naa ko si gbeyin. Lara awon olorin ti won forin aladun da awon eeyan laraya lojo naa ni:Soul Winner, Biola Fame, Biyi Samuel, Ayanfe Jesu ati Arewa Ayangbayi to lulu nibi eto yii. Die ninu awon eeyan to wa nibe ree o




No comments:

Post a Comment

Adbox