IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Saturday, 8 September 2018

ESTHER IGBEKELE FORIN DARA NIBI AYEYE IGBEYAWO OMO ABEY FAGBORO, AGBA SOROSORO ORI RADIO








Ojo nla lojo ti agba-oje sorosoro ori radio, Oloye Abbey Fagboro, ko ni i  gbagbe boro lojo Abameta, Satide, anaa. Ojo yii ni baba naa sin omo e, Oluwadamilola lo sile oko, Olumide lo gbe arewa obinrin yii niyawo. 



Lati ojo Eti, Fraide layeye igbeyawo yii ti bere, ti gbajumo olorin emi nni, Efanjeliisi Esther Igbekele fi orin aladun da awon eeyan laraya nibi asekagba ayeye naa to waye ni gbongan 'Palmroof' to wa ni Alakuko lojo Abameta.

Nibi ti gbongan yii tobi de, inu e ko gba eeyan, bawon sorosoro se kunbe bamu, lawon ebi, ore atawon afenifere naa ko gbeyin nibe.

Gbajugbaja sorosoro ori radio ati telifisan, Ambassado Yomi Mate tawon  eeyan tun mo si Ifa-n-kale-luyah lo dari ayeye igbeyawo naa.

Eni to ba ri Oloye Abbey Fagboro atiyawo e lojo yii yoo mo pe inu won dun koja aaye.
 Die ninu awon foto ti Ojutole ya nibe ree

















Toko-tiyawo atawon ore won





   

No comments:

Post a Comment

Adbox